Ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn hadiisi

Dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n gbe ọwọ rẹ mejeeji si deedee ejika rẹ mejeeji ti o ba ti bẹ̀rẹ̀ irun,
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ mi ni ataya, ti atẹlẹwọ mi wa laaarin atẹlẹwọ rẹ mejeeji, gẹgẹ bi o ṣe maa n kọ mi ni Surah ninu Kuraani
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Irẹ Ọlọhun dajudaju emi wa iṣọra pẹlu Rẹ kuro nibi iya saare, ati nibi iya ina, ati nibi fitina iṣẹmi ati iku, ati nibi fitina al-Masiihu ad-Dajjāl
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Al-Lahumma Bā`id Baynī Wa Bayna Khaţāyāya Kamā Bā`adta Bayna Al-Mashriqi Wa Al-Maghribi
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ṣé ki n sọ ọrọ kan fun yin nipa dajjal, ti Anabi kan ko sọ nipa rẹ ri fun ijọ rẹ? O jẹ olójú kan, o maa mu nnkan ti o da bii alujanna ati ina wa pẹlu rẹ,
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Dajudaju àpèjúwe olubajokoo rere ati olubajokoo burúkú da gẹgẹ bi ẹni ti o gbe almisiki ati eni ti o n fẹ ina alagbẹdẹ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹ yára si awọn iṣẹ daadaa siwaju ki awọn fitina kan ti yio da bii oru ti o ṣokunkun gan o to de,
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o ṣe pe ti o ba fẹ wọ aaye ẹgbin yio sọ pe: «Allaahummọ inni a‘uudhu biKa minal khubuthi wal khabaaithi
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Imọtaraẹni-nikan maa wa ati awọn àlámọ̀rí kan ti ẹ maa takò wọn" wọn sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ki ni nnkan ti o maa pa wa láṣẹ? O sọ pe: "Ẹ maa pe ẹtọ ti o jẹ dandan fun yin, ẹ si maa beere lọwọ Ọlọhun nnkan ti o jẹ ti yin
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Dajudaju Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o ṣe pe ti o ba n kirun yio fi alafo si aarin ọwọ rẹ mejeeji titi ti abiya rẹ mejeeji o fi han
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Dinar (owo) ti o lọla julọ ti ọmọniyan n na ni dinar (owo) ti o na fun awọn ara ilé rẹ, ati owo ti o na lori nkan ọ̀gùn rẹ lọ si oju-ọna Ọlọhun, ati owo ti o na lori awọn ẹmẹwa rẹ ni oju-ọna Ọlọhun
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Nígbàtí ẹnikan nínú yín bá lá àlá tí ó nifẹ sí, dajudaju ala naa lati ọdọ Ọlọhun ni ó ti wá, nitori naa ki ó fi ọpẹ fún Allah (Ọlọhun) lori rẹ, kó sì sọ ọ́ fún ẹniti ó bá fẹ́, ṣugbọn tí ó bá lá àlá tí ó yàtọ̀ sí eleyii, ti kò sì wuu, dajudaju lati ọdọ èṣù ni o ti wá, ki iru ẹni bẹẹ yaa bẹ Ọlọhun fún ààbò àti iṣọ nibi aburu àlá naa, bẹẹ ni ki ó má rọ́ àlá náà fún ẹnikankan, ti kò bati rọ ọ fún ẹnikankan àlá náà kò ní kó ìnira ba a
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Eemọ ni alamọri mumini, dajudaju gbogbo alamọri rẹ oore ni, iyẹn o si si fun ẹnikankan ayaafi mumini
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Alaye iwẹ latara janaba
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o ṣe pe ti o ba ti fẹ wẹ janaba, yio fọ ọwọ rẹ mejeeji, yio si tun ṣe aluwala rẹ ti maa n ṣe fun irun, lẹyin naa yio wẹ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba sin, o maa n gbe ọwọ rẹ- tabi aṣọ rẹ- si ẹnu rẹ, ti o maa fi rẹ ohun rẹ nilẹ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Apejuwe ẹni ti o duro nibi aala Ọlọhun ati ẹni ti o ko sinu rẹ, da gẹgẹ bi apejuwe awọn ijọ kan ti wọn mu aje lori ọkọ oju-omi, ni apakan wọn wa bọ si oke rẹ ti apakan wọn si wa ni isalẹ rẹ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Mo jẹ ọkùnrin kan ti o maa n da atọ ireke lọpọlọpọ, mo maa n tiju lati beere lọwọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nitori ipo ọmọbinrin rẹ, mo wa pa Miqdad ọmọ Al-Aswad láṣẹ o si beere lọwọ rẹ, o sọ pe: "O maa fọ nnkan ọmọkunrin rẹ yoo si ṣe aluwala
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹ ko gbọdọ sọ pe: Ti Ọlọhun ba fẹ ati ti lagbaja ba fẹ, ṣùgbọ́n ẹ maa sọ pe: Ti Ọlọhun ba fẹ lẹyin naa ti lagbaja ba fẹ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Dajudaju ẹ ma maa tẹle oju ọna awọn ti wọn ṣáájú yin, ni odiwọn ìbú atẹlẹwọ si ibu atẹlẹwọ, ni odiwọn apa si apa
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹnikẹni ti ó bá ṣamojuto ọmọ obinrin meji tabi tí ó tọ́ wọn dagba titi ti wọ́n fi di ẹni ọkunrin, irufẹ ẹni bẹẹ yóò wá ní ọjọ igbende ti èmi rẹ̀ yóò wà papọ̀" Anọbi pa ọmọnika rẹ papọ̀ mọ́nrawọn
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹ ko lee wọ alujanna titi ti ẹ fi maa gbagbọ, ati pe e ko lee gbagbọ titi ti ẹ fi máa nífẹ̀ẹ́ ara yin, ẹ wa jẹ ki n juwe yin si nkankan ti o jẹ pe ti ẹ ba ṣe e ẹ máa nífẹ̀ẹ́ ara yin? Ẹ maa tan salamọ ka laarin ara yin
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ti ki báa ṣe pe kin má ko waala bá awọn olugbagbọ ododo ni - tabi awọn ijọ mi ni - mi o ba pa wọ́n laṣẹ lati máa rin pako ni gbogbo asiko Irun kọọkan
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ewo ninu iṣẹ ni Ọlọhun nifẹẹ si julọ? O sọ pe: "Irun kiki ni asiko rẹ", o sọ pe: Lẹyin naa èwo? O sọ pe: "Lẹyin naa ṣíṣe daadaa si awọn obi mejeeji" o sọ pe: Lẹyin naa èwo? O sọ pe: "Jija ogun si oju ọna Ọlọhun
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Dajudaju arakunrin kan jẹun lọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pẹlu ọwọ osi rẹ, o sọ pe: "Jẹun pẹlu ọwọ ọtun rẹ", o sọ pe: Mi ko ni ikapa, o sọ pe: "O ò sì nii ní ikapa
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹni ti o ba pepe lọ si ibi imọna, iru awọn ẹsan ti o n bẹ fun ẹni ti o ba tẹle e, maa wa fun un ninu ẹsan, ti ìyẹn ko nii din nnkan kan ku ninu awọn ẹsan wọn
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Kosi ọjọ kan ti awọn ẹrusin yóò jí ní àárọ̀ ayaafi kí ó jasipe awọn malaika (iranṣẹ Ọlọhun) meji yoo sọkalẹ sí ọdọ ẹnikọọkan, ọkan ninu awọn mejeeji yóò máa ṣọ pe: "Irẹ Ọlọhun dakun bá mi ṣe iropo owo fún ẹni tí n nawo rẹ, bẹẹ ni ikeji yóò máa ṣọ pe: "Bami fi iparun ati ibajẹ sinu owo ẹni tí ó kọ̀ lati ma na owo, tí ó wowọ́ mọ́n owo kankan
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Fifi ẹyẹ furamọ aburu ati oore ẹbọ ni, fifi ẹyẹ furamọ aburu ati oore ẹbọ ni, fifi ẹyẹ furamọ aburu ati oore ẹbọ ni,- lẹẹmẹta-", ko si ninu wa afi, ṣùgbọ́n Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- n mu u lọ pẹlu igbarale Ọlọhun
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
ni a wa sọ pe: Iwọ ni olowo wa, ni o wa sọ pe: "Allāhu ni Olowo", a sọ pe: ati ọlọlajulọ inu wa, ati ọlọrọ julọ inu wa, ni o wa sọ pe: «Ẹ maa sọ awọn ọrọ yin, tabi apakan awọn ọrọ yin, ẹ ma jẹ ki esu o lo yin (ki o gbe yin kọja aala)
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹyin eniyan, ẹ ṣọ́ra kuro nibi aṣeju nibi ẹsin, dajudaju nnkan ti o pa àwọn ti wọn ṣíwájú yin run ni aṣeju nibi ẹsin
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ko si àkóràn, tabi fifi ẹyẹ fura mọ aburu, tabi fifi ẹyẹ owiwi fura mọ ìṣẹ̀lẹ̀ àjálù, tabi fifi oṣu Safar fura mọ aburu, ki o si sa fun adẹtẹ gẹgẹ bi o ṣe maa n sa fun kinihun
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Mo fi Ọlọhun bura, ki Ọlọhun fi arákùnrin kan ṣoṣo mọna latara rẹ, o loore fun ẹ ju ki o ni ràkúnmí pupa lọ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Irẹ ọmọ-iya baba mi, sọ pe: Laa illaha illā Allāhu, gbolohun kan ni ti maa fi jẹrii gbe ọ ni ọdọ Allāhu
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ko si akoran, ko si si ifi ẹyẹ fura mọ daadaa tabi aburu, ati pe mo fẹ́ràn fah'lu, o sọ pe wọn sọ pe: Kí ni fah'lu? O sọ pe: "Ọrọ ti o daa
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- dajudaju o sọ nipa awọn Ansar pe: "Ẹnikan ko nii nífẹ̀ẹ́ wọn afi olugbagbọ, ẹnikan ko si nii korira wọn afi sobẹ-ṣelu, ẹni ti o ba nífẹ̀ẹ́ wọn, Ọlọhun maa nifẹẹ rẹ, ẹni ti o ba si korira wọn Ọlọhun maa korira rẹ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
o ṣe aluwala fun wọn ni aluwala Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
O ti to fun ẹ ki o fi ọwọ rẹ mejeeji ṣe bayii» lẹyin naa ni o fi ọwọ rẹ mejeeji lu ilẹ ni ẹẹkan, lẹyin naa ni o fi osi pa ọtun, ati ẹyin ọwọ rẹ mejeeji ati oju rẹ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Dajudaju awọn eniyan ti wọn ba ti ri alabosi, ti wọn ko si gba a mu ni ọwọ rẹ mejeeji, o sunmọ ki Ọlọhun fi iya kan lati ọdọ Rẹ kari wọn
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Mo maa n wẹ emi ati Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ninu igba kan naa ti awa mejeeji si jẹ ẹni ti o ni janaba lara, o maa n pa mi láṣẹ, ti maa si ro iro, ti o si maa n sunmọ mi ti mo si jẹ ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu,
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Mo ṣadehun fun ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori jijẹrii pe ko si ẹnikan ti ijọsin tọ si afi Ọlọhun, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni, ati gbigbe irun duro, ati yiyọ saka, ati gbigbọ ati itẹle, ati ṣíṣe iṣiti fun gbogbo Musulumi
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹ bẹru Ọlọhun Oluwa yin, ẹ ki irun wakati marun-un yin, ẹ gba awẹ oṣu yin, ẹ yọ saka awọn dukia yin, ẹ tẹle adari àlámọ̀rí yin ẹ maa wọ alujanna Olúwa yín
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ṣé ki n tọka yin si nnkan ti Ọlọhun fi maa n pa awọn àṣìṣe rẹ, ti O si fi maa n gbe awọn ipo ga?
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ṣé ki n fun yin ni iro nipa eyi ti o daa julọ ninu awọn iṣẹ yín, ati eyi ti o mọ julọ ninu rẹ lọdọ Oluwa yin, ati eyi ti o ga julọ ninu rẹ ninu awọn ipo yin
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Tọ mi sọ́nà lori iṣẹ kan ti mo ba ṣe e maa wọ alujanna, o sọ pe: "Maa jọsin fun Ọlọhun ki o si ma da nnkan kan pọ mọ Ọn, ki o maa gbe irun ti a ṣe ni dandan duro, ki o maa yọ saka ti a ṣe ni ọran-anyan, ki o maa gba awẹ Ramadan
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
”O ti jere ti o ba sọ ododo”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Eyi ti o loore julọ ninu ọjọ ti oorun yọ nibẹ ni ọjọ Jímọ̀
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Imu kan gbolẹ, Imu kan gbolẹ, Imu kan gbolẹ", wọn sọ pé: Tani? Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, o sọ pe: "Ẹni ti o ba obi rẹ mejeeji nigba ogbo, ọkan ninu awọn mejeeji tabi awọn mejeeji ti ko wa wọ alujanna
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
àwọn MUFARRIDUUN ti ṣíwájú
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Fiforikanlẹ fun Ọlọhun lọpọlọpọ jẹ dandan fun ẹ, dajudaju o ko nii forikanlẹ fun Ọlọhun ni iforikanlẹ ẹẹkan, afi ki Ọlọhun fi gbé ẹ ga nipo, ki O si fi ba ẹ pa ẹṣẹ rẹ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Gbogbo ijọ mi ni wọn maa ṣọ kuro nibi aburu ayaafi awọn alaṣehan
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
lori ki ni a maa ṣadehun fun ẹ? O sọ pe: "Lori pe ẹ ma maa jọsin fun Ọlọhun ẹ ko si gbọdọ da nnkan kan pọ mọ Ọn, ati awọn irun maraarun-un, ẹ si gbọdọ maa tẹle- o wa sọ ọrọ kan ti o pamọ ni jẹjẹ- ẹ ko si gbọdọ beere nnkan kan lọwọ awọn eniyan
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹni ti o ba kirun tutu mejeeji o maa wọ alujanna
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Musulumi ti wọn ba bi i leere ninu saare: O maa jẹrii pe ko si ẹnikan ti ijọsin tọ si afi Allahu ati pe dajudaju Muhammad ojisẹ Ọlọhun ni
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Wọn pa mi láṣẹ lati ba awọn eniyan ja titi wọn maa fi jẹrii pe ko si ẹnikan ti ijọsin tọ si afi Allahu, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni, ti wọn si n gbe irun duro, ti wọn si n yọ saka
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹni ti o n gun nkan ni o maa salamọ si ẹni ti o n rin, ẹni ti o n rin ni o máa salamọ si ẹni ti o jokoo, awọn ti onka wọn kere ni wọ́n maa salamọ si awọn ti onka wọn pọ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Dajudaju Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn maa n tẹ ọwọ Rẹ ni oru lati gba tuuba ẹni ti o ba da ẹṣẹ ni ọsan, O si tun maa n tẹ ọwọ Rẹ ni ọsan lati gba tuuba ẹni ti o da ẹṣẹ ni oru titi oorun o fi yọ ni ibi ti o ti maa n wọ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Irun ọkunrin kan pẹ̀lú janmọọn ju irun rẹ nile lọ ati Irun rẹ ni ọja lọ pẹlu ipò ogún lé ní nǹkan kan
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Gbogbo ibi ti àwọn eegun ti pàdé pọ ni ara ọmọniyan ni saara jẹ dandan le e lori nibẹ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹsẹ mejeeji ẹru kan ko nii yẹ ni ọjọ igbedide titi ti wọn o fi bi i nipa ọjọ ori rẹ nibo ni o pari rẹ si, ati nipa imọ rẹ kini o fi ṣe, ati nipa dukia rẹ nibo ni o ti ko o jọ ati pe nibo ni o na an si, ati nipa ara rẹ nibo ni o lo o si
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹ sọ fun mi ti akeremọdo kan ba wa ni ẹnu ọ̀nà ẹni kọọkan ninu yin ti o n wẹ nibẹ ni ojoojumọ lẹẹmarun-un, njẹ ìyẹn le ṣẹ nǹkan kan kù nínú ìdọ̀tí rẹ bi?
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Apejuwe awọn Mumuni nibi nini ifẹ ara wọn ati kikẹ ara wọn ati nini aanu ara wọn da gẹgẹ bi apejuwe odidi ara, nigba ti orike kan ba n ke irora gbogbo ara yoku ni yio para pọ pẹlu rẹ nibi aisun ati igbona
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹ pa awọn ọmọ yin láṣẹ pẹlu irun ti wọn ba ti wa ni ọmọ ọdun meje, ẹ na wọn lori rẹ ti wọn ba ti wa ni ọmọ ọdun mẹwaa, ẹ ṣe opinya laaarin wọn nibi awọn ibusun
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ko si nkankan ti o wuwo julọ ninu oṣuwọn Mumuni ni ọjọ igbedide ti o to iwa daadaa, ati pe dajudaju Ọlọhun a maa korira onibajẹ onisọkusọ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- jade si wa, a sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, a ti kọ bi a ṣe maa salamọ si ẹ, bawo ni a ṣe maa ṣe asalatu fun ẹ?
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ko si irun fun ẹni ti ko ba ka Faatiha
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Mumini alagbara ni oore o si tun jẹ ẹni ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si ju Mumini ọlẹ lọ, ọkọọkan wọn si ni oore wa lara rẹ,
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Adura ti Anabi maa n ṣe loorekoore ju ni:(( “Ọlọ́hun, Oluwa wa, fun wa ni oore ni aye, ati rere ni ìgbẹ̀yìn, ki O si daabo bo wa nibi iya ina”.))
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Olori iwaforijin
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹ paya abosi, nitori pe abosi jẹ awọn okunkun ni ọjọ igbedide, ẹ paya ahun, nitori pe ahun lo pa awọn ti wọn ṣáájú yin run,
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Dajudaju arakunrin kan bi Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - leere pe: Isilaamu wo lo fi n loore julọ? O sọ pe: «Ki o maa funni ni ounjẹ, ki o si tun maa salamọ si ẹni ti o mọ ati ẹni ti o ko mọ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Gbogbo yín ni adaranjẹ, ẹni ti a maa beere awọn ti o dajẹ lọwọ rẹ ni ẹni kọọkan yín,
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
mo wa fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, ẹ o maa tẹle ilana awọn ti wọn ṣaaju yin
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Arakunrin kan wa si ọdọ Anabi Ọlọhun -ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a-, o si ba a sọrọ nipa ọrọ kan, o sọ pe: “Ohunkohun ti Ọlọhun ba fẹ, ti iwọ anabi si fẹ. ” Nígbà náà ni Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, wí pé: “ṣé iwọ o fi mí ṣe bakannaa pẹlu Ọlọ́run ni? Sọ pé: Ohunkóhun tí Ọlọ́run nìkan ṣoṣo bá fẹ́”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹni ti o maa le koko julọ ninu awọn eniyan ni ti iya ni ọjọ igbedide ni awọn ti wọn n ṣe afijọ ẹda Ọlọhun
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
{Qul Uwal Laahu ahad} ati Al-mu‘awwidhatayn (Falaqi ati Naasi) nigba ti o ba di irọlẹ ati ti o ba di afẹmọjumọ ni igba mẹta, yio to ọ nibi gbogbo nkan
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Sọ pe: Laa ilaaha illallohu wahdaHu laa shariika laHu, Allahu Akbar kabeeran, wal amdulillah katheeran, Subhaanallah Robbil 'aalameen, laa haola wa laa quwwata illa billahil Azeezil Hakeem
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ko si ninu ọmọniyan to jẹ musulumi ti irun ọran-anyan kan wa ba a, ti o wa ṣe aluwala rẹ daadaa ati ipaya rẹ ati rukuu rẹ, afi ki o jẹ ipa ẹṣẹ rẹ fun nnkan ti o ṣíwájú ninu awọn ẹṣẹ, niwọn igba ti ko ba mu ẹṣẹ nla wa, gbogbo igba si ni ìyẹn maa ri bẹ́ẹ̀
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Àpèjúwe Mumini ti n ka Kuraani da gẹgẹ bii èso utrujjah, ti oorun rẹ daa, ti itọwo rẹ naa si daa, àpèjúwe mumini ti kii ka Kuraani da gẹgẹ bii èso dabinu, ti ko ni oorun, ti itọwo rẹ si dùn
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Awọn gbolohun ẹyin irun kan n bẹ ti o ṣe pe ẹni ti o ba sọ wọn - tabi ti o ṣe wọn - ni ẹyin gbogbo irun ọranyan, ko ni mofo, subhānallāh ọgbọn ati mẹta, ati alhamduliLlāhi ọgbọn ati mẹta, ati Allāhu akbar ọgbọn ati mẹẹrin
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹni ti o ba sọ nigba ti o n gbọ oluperun pe ash-hadu an laa ilaaha illa Allāhu wahdahu laa sharika laHu, wa anna muhammadan ‘abduHu wa rosuuluhu, rodiitu bil Laahi robban wa bi muhammadin rosuulan wa bil Isilaami diina, wọn a fi ori ẹṣẹ rẹ jin in
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ọmọ Adam pe Mi ni opurọ, ko si tọ fun un, o si bu mi, ko si tọ fun un
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹni ti o ba mu aayo mi ni ọta, Mo ti kede ogun pẹlu rẹ, ati pe ẹru Mi o nii sunmọ Mi pẹlu nkankan ti Mo nífẹ̀ẹ́ si ju nkan ti Mo ṣe ni ọranyan fun un lọ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹni ti o ba sọ agbekọ, o ti ṣe ẹbọ (mu orogun pẹlu Ọlọhun)
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Dajudaju arakunrin kan ṣe aluwala ni o wa fi aaye eekanna silẹ nibi ẹsẹ rẹ, ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa ri i ti o si sọ pe: «Pada ki o si lọ ṣe aluwala rẹ daadaa» ni o ba pada, lẹyin naa ni o kirun
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Awọn iran eniyan meji kan wa ninu ara ina ni wọn, mi ko ri wọn, ijọ kan ni ti awọn ọrẹ n bẹ pẹlu wọn ti wọn da gẹgẹ bi awọn iru maluu ti wọn maa n fi i na awọn eniyan, ati awọn obinrin kan wọn maa wọ aṣọ wọn si maa wa ni ihoho, ti wọn maa n mu ẹlòmíràn yẹ gẹrẹ, ti awọn gan ti yẹ̀ gẹ̀rẹ̀
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ọkunrin o gbọdọ maa wo ihoho ọkunrin, obinrin naa o si gbọdọ maa wo ihoho obinrin
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Awọn malaika o nii maa bẹ pẹlu ikọ kan ti aja ati agogo ba wa pẹlu wọn
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
A jẹ ẹni ti kii ka omi ti awọ rẹ f'ara pẹ dúdú, ati omi alawọ iyeye lẹ́yìn imọra si nǹkan kan
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹ koraro ni odiwon igba ti nnkan oṣu rẹ ba fi de ọ mọle, lẹyin naa ki o wẹ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Iwẹ ọjọ Jimoh jẹ dandan lori gbogbo ẹni ti o ti balaga, ki o si fi pako run awọn eyin rẹ, ki o si lo lọ́fíńdà ti o ba ri
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Musulumi ni ẹni ti awọn musulumi la nibi ahọn rẹ ati ọwọ rẹ, ati pe Al-muhaajiru ni ẹni ti o yan nkan ti Ọlọhun kọ lodi
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Obinrin ko gbọdọ ṣe irin-ajo ti o to ọjọ meji ayaafi ki ọkọ rẹ tabi eleewọ rẹ o wa pẹlu rẹ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹni ti o ba ṣe afọmọ fun Ọlọhun (Subhānallāh) ni ẹyin gbogbo irun kọọkan ni igba mẹtalelọgbọn, ti o si tun dupẹ fun Ọlọhun (AlhamduliLlāhi) ni igba mẹtalelọgbọn, ti o tun wa gbe titobi fun Ọlọhun (Allāhu akbar) ni igba mẹtalelọgbọn, ìyẹn jẹ ọgọrun din ẹyọkan, ti o wa sọ ni ipari ọgọ́rùn-ún pe: Lā ilaha illā Allāhu wahdahu lā sharīka laHu, laHul mulku, wa laHul hamdu, wa Huwa alā kulli shayhin qadīr, wọn o fi ori gbogbo ẹṣẹ rẹ jin in kódà ki o to deede fóòmù ori omi okun
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹni ti o ba ka āyatul kursiyyu ni ẹyin irun ọranyan kọọkan, ko si nkan ti yio di i lọwọ wiwọ al-jannah ayaafi ki o ku
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
O daju pe ẹsin yii a de gbogbo ibi tí oru ati ọsan de, ati pe Ọlọhun o nii fi ile kankan silẹ bóyá ilé alámọ̀ ni abi ilé onírun ayafi ki O mu ẹsin yii wọ ibẹ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ti ẹnikẹni ninu yin ba ṣe iyemeji nibi irun rẹ, ti ko si mọ iye ti o ki boya mẹta ni tabi mẹrin, ki o yaa ju iyemeji naa nù, ki o mọ irun rẹ lori nnkan ti o da a loju, lẹyin naa, o maa forikanlẹ ni iforikanlẹ ẹẹmeji ṣíwájú ki o to salamọ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Gbogbo nkan ti o ba ti n muni hunrira ọti ni, ati pe gbogbo nkan ti o ba ti n muni hunrira eewọ ni, ati pe ẹni ti o ba mu ọti ni aye ti o wa ku ni ẹni ti o kúndùn rẹ ti ko tuuba, ko nii mu un ni ọjọ ikẹyin
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, mi ko fi ẹṣẹ kankan sílẹ̀ láì dá, o sọ pe: “Njẹ ṣe ko ki n ṣe pe o n jẹrii pe ko si ẹni ti ìjọsìn tọ si òdodo afi Allahu ni, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni?
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
ko fi ọjọ kan sọ pé: Irẹ Oluwa mi, fori awọn àṣìṣe mi jin mi ni ọjọ ẹsan
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Njẹ ẹ mọ nnkan ti Oluwa yin sọ?” Wọn sọ pé: Ọlọhun ati ojiṣẹ rẹ ni wọn ni imọ julọ, o sọ pe: “O n bẹ ninu awọn ẹru Mi ẹni ti o ji ni onigbagbọ ati ẹni tí o ji ni alaigbagbọ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Dajudaju a n ri ninu ẹ̀mí wa nnkan ti ẹnikẹni nínú wa ko lee sọ ọ, o sọ pe: “Ṣé ẹ ti ri i?” Wọn sọ pé: Bẹẹni, o sọ pe: “Iyẹn ni igbagbọ ododo ti ko rùjú
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
ọpẹ ni fun Ọlọhun ti O da ete rẹ pada si royiroyi
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Èṣù a maa wa ba ẹnikan ninu yin, yoo si sọ pe: Ta ni o ṣẹda èyí? Ta ni o ṣẹda èyí? Titi yoo fi sọ pé: Ta ni o ṣẹda Oluwa rẹ? Ti o ba ti ba a de ibẹyẹn, ki o yaa wa iṣọra pẹlu Ọlọhun ki o si jawọ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Mẹ́fà ni àwọn iṣẹ́, mẹrin si ni àwọn èèyàn, méjì maa n sọ nǹkan di dandan, ati èyí ti o ṣe pe déédéé iṣẹ ti eeyan ba ṣe naa ni ẹsan rẹ, ati eyi ti o ṣe pe iṣẹ rere kan pẹlu ẹsan mẹ́wàá ni, ati eyi ti o ṣe pe iṣẹ rere kan pẹlu ẹẹdẹgbẹrin ẹsan ni
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Dajudaju Ọlọhun ko nii ṣe abosi olugbagbọ kan ni ti daadaa ti o ba ṣe, wọn yoo fun un ni ẹsan rẹ ni aye, wọn si tun maa san an ni ẹsan pẹlu rẹ ni ọrun
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
O gba Isilaamu lori nnkan ti o ṣáájú ninu daadaa”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Dajudaju Ọlọhun maa n fẹ́ lati mu awọn ofin idẹkun Rẹ wa, gẹgẹ bi O ṣe nífẹ̀ẹ́ lati mu awọn eyi ti o jẹ dandan wa”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Apejuwe ṣọbẹ-ṣelu da gẹgẹ bii apejuwe aguntan ti o n lọ ti o n bọ laaarin agbo aguntan meji, yoo lọ sibi fun ìgbà kan, yoo tun lọ si ọ̀hún nigba mii”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Dajudaju igbagbọ maa n gbó ninu ikun ẹni kọọkan yin gẹgẹ bí aṣọ ṣe maa n gbó, ki ẹ ya maa beere lọdọ Ọlọhun lati sọ igbagbọ di tuntun ninu awọn ọkan yin”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Dajudaju ninu awọn ami ọjọ igbende ni ki wọn ka imọ kúrò nílẹ̀, ki aimọkan si pọ, ki ṣina si pọ, ti ọti mimu si maa pọ, ti onka awọn ọkunrin si maa kere, ti onka awọn obinrin si maa pọ titi ti o fi maa jẹ pe ọkùnrin kan ni yoo maa bẹ fun aadọta obinrin”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ọjọ igbedide ko nii to titi ti arakunrin o fi maa kọja nibi saare arakunrin, o maa sọ pé: Mii ba si wa ni ipo rẹ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Ọjọ igbende ko nii to titi ẹ fi maa ba awọn Juu ja, titi okuta ti Juu wa lẹyin rẹ fi maa sọ pé: Irẹ Musulumi, eleyii ni Juu lẹyin mi, pa a”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Mo fi ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, o maa ku díẹ̀ ki ọmọ Maryam sọkalẹ si aarin yin ni adajo oluṣedeedee, ti o maa run agbelebuu, ti o maa pa ẹlẹ́dẹ̀, ko nii jẹ ki wọn san isakọlẹ mọ, ti owo maa pọ̀ titi ẹni kankan ko fi nii gba a mọ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Ọjọ igbende ko lee to titi orun fi maa yọ lati ibuwọ rẹ, ti o ba ti yọ ti awọn eniyan ti wa ri i, gbogbo wọn maa gbagbọ lapapọ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Aye o nii parẹ titi ti igba o fi sunmọ ara wọn
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ọlọhun a gba ilẹ mu, yoo si tun ka sanmọ pẹlu ọwọ ọtun Rẹ, lẹyin naa ni Yoo waa sọ pe: Emi ni Ọba, gbogbo ọba (olukapa) ori ilẹ̀ da?
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Abàtà mi, ìrìn oṣù kan ni, omi rẹ̀ funfun ju wàrà lọ, òórùn rẹ̀ dùn ju alumisiki lọ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Maa wa nibi adágún naa ki n le ri ẹni tí o maa wa si ọdọ mi ninu yin, wọn maa mu awọn èèyàn kan kúrò ni tòsí ọdọ mi, mo maa wa sọ pé: Irẹ Oluwa mi, ara ìjọ mi ni wọn
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Mo fi Ẹni tí ẹmi Muhammad wa lọ́wọ́ Rẹ bura, àwọn ife ìmumi rẹ pọ̀ ju onka awọn irawọ sanmọ lọ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Wọn maa mu ikú wá ni ìrísí àgbò ti o ni dúdú ati funfun lára
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Iná yin jẹ ẹ̀yà kan nínú ẹ̀yà àádọ́rin ti ina Jahannama ni
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ojiṣẹ Ọlọhun- kí ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba wa sọrọ, olódodo ni, ẹni tí a sọ òdodo fún si ni: “Wípé wọ́n maa kó ẹ̀dá ẹnikan nínú yín jọ sínú ikùn ìyá rẹ̀ fún ogójì ọjọ́
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Gbogbo nnkan pẹlu kádàrá ni, titi dórí ikagara ati ijafafa, tàbí ijafafa ati ikagara”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Ti Ọlọhun ba kádàrá fun ẹrú kan pé o maa kú si ilẹ̀ kan, O maa jẹ ki o ni bukaata si i.”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹni ti o ba mọọmọ parọ mọ mi, ki o yaa lọ wa ibùjókòó rẹ ninu ina
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
emi ni Dimaam ọmọ Tha’labah, láti ìdílé Banuu Sahd ọmọ Bakr
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- dárúkọ nǹkan kan, o wa sọ pé: “Ìyẹn nigba ti imọ bá lọ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹ má gba ọ̀rọ̀ àwọn Júù àti Kristẹni ni ododo, ẹ si ma pe e ni irọ, ki ẹ sọ pé: {A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa}
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Ẹ ma kọ́ imọ lati le maa fi ba àwọn onimimọ ṣe iyanran, tabi lati le baa maa fi ja àwọn omugọ níyàn
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Ọlọhun fi àkàwé kan lélẹ̀ nipa ojú ọ̀nà tààrà kan
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Wọn sọ ìmísí kalẹ fun ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nígbà tí o pe ọmọ ogójì ọdún
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kii mọ gígé àsopọ̀ suura titi ti {BISMILLAAHI RAHMAANI RAHEEM} fi maa sọkalẹ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni nínú yín yóò fẹ́, nígbà tí ó bá padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ará ilé rẹ̀, láti rí ràkúnmí aboyún mẹ́ta ti wọn tobi ti wọn sanra ni ọdọ wọn?
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Wọn maa sọ fun onikuraani pe: Máa kà, máa gòkè, maa ké gẹgẹ bi o ṣe maa n ké e ni aye, dájúdájú ibùgbé rẹ wa nibi igbẹyin aaya ti o n ka”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Ẹni tí ba n ka Kuraani sókè da gẹgẹ bii ẹni ti n ṣe sàárà gbanngba, ẹni tí n ka Kuraani jẹ́ẹ́jẹ́ da gẹgẹ bii ẹni ti n ṣe saara kọ̀kọ̀”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
maa n gba aaya mẹ́wàá lọ́dọ̀ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- àwọn ko nii gba mẹ́wàá miiran titi ti àwọn fi maa mọ imọ ati iṣẹ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Irẹ Abu Al-Munzir, ǹjẹ́ o mọ aaya wo ninu tira Ọlọhun ti o wa pẹlu rẹ ni o tobi julọ?”, o sọ pe: Mo sọ pé: {Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá} [Al-Baqarah: 255]. O sọ pe: O wa fi ọwọ́ lu mi láyà, o wa sọ pé: “Mo fi Ọlọhun búra, o kú oriire imọ naa, ki Ọlọhun ṣe e ni irọrun fun ẹ, irẹ Abu Al-Mundhir”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Pe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba ti fẹ sùn ni gbogbo alẹ́, o maa pa atẹlẹwọ rẹ méjèèjì pọ̀, lẹyin naa o maa fẹnu fẹ atẹ́gùn túẹ́túẹ́ sinu méjèèjì, o maa wa ka sínú méjèèjì: {Qul Uwal Loohu Ahad}, ati {Qul Ahuuzu bi Robbil falaq}, ati {Qul Ahuuzu bi Robbin naas}
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Awọn Juu ni awọn ti a binu si, ti awọn Nasara jẹ awọn ẹni anu
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ti o ba ti ri awọn ti n tẹle ohun ti o ruju ninu ẹ, àwọn ti Ọlọhun sọ nìyẹn, ki ẹ ṣọ́ra fun wọn
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ko si ẹnìkankan ti yio da ẹṣẹ kan, lẹyin naa ni o wa dide ti o si ṣe imọra, lẹyin naa ni o wa kirun, lẹyin naa o wa aforijin Ọlọhun, ayaafi ki Ọlọhun ṣe aforijin fun un
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Wọ́n maa ṣírò ijanba ti wọn ṣe fun ẹ, ati bi wọn ṣe yapa àṣẹ rẹ, ati irọ́ ti wọn pa fun ẹ, ati ìyà ti o fi jẹ wọn
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Njẹ Ẹni tí Ó mu un rìn lori ẹsẹ méjèèjì ni ayé ko ni ikapa lati jẹ ki o fi ojú rẹ rìn ni Ọjọ́ Àjíǹde ni?
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Sọ pe: LAA ILAAHA ILLALLOOH, maa fi jẹ́rìí fun ọ ni Ọjọ́ Àjíǹde
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Dajudaju nkan ti o n sọ ti o si n pepe si, nkan ti o daa ni, ti o ba fun wa niroo pe aforijin n bẹ fun nkan ti a ṣe
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Lọ ba a ki o si sọ fun un pe: Dajudaju irẹ ko si ninu awọn ọmọ ina, ṣugbọn o wa ninu awọn ọmọ alujanna
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Mo pe ẹyin eeyan, dajudaju Ọlọhun ti gbe kuro fun yin igberaga igba aimọkan ati ṣiṣe iyanran wọn pẹlu awọn baba wọn
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
(Thumma latus alunna yauma-izin ‘anin na’eem)
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Awọn eniyan kan maa wa ni igbẹyin ijọ mi, ti wọn maa maa sọ fun yin nnkan ti ẹyin gangan tabi awọn baba yin ko gbọ, ẹ ṣọra fun wọn ”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Maa kọ, mo fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, nkankan o nii jade nibẹ (ẹnu rẹ) ayaafi ododo
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti maa n ṣe aluwala fun gbogbo irun
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe aluwala ni ẹyọkọọkan
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe aluwala lẹẹmeji meji
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ti ẹnikẹni ninu yin ba ri nkankan ninu ikun rẹ, ti o wa ru u loju boya nkankan jade nibẹ tabi ko jade, ki o ma ṣe jade kuro ni masalaasi titi ti yio fi gbọ ohun, tabi ki o gbọ oorun
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹtọ ni lori gbogbo Musulumi ki o wẹ ni ọjọ kan ninu gbogbo ọjọ meje, ti yio wẹ ori rẹ ati ara rẹ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Mo lọ ba Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe mọ fẹ gba Isilaamu, o wa pa mi láṣẹ lati wẹ pẹlu omi ati ewe sidiru
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ti ẹ ba ti gbọ oluperun ki ẹ yaa maa sọ gẹgẹ bi o ṣe n sọ, lẹyin naa ki ẹ wa ṣe asalaatu fun mi
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹni ti o ba kọ mọsalasi kan fun Ọlọhun, Ọlọhun maa kọ iru rẹ fun un ninu alujanna”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Irun kan ti a ba ki ni mọsalasi mi yii loore ju ẹgbẹ̀rún irun lọ ti a ki ni ibi ti o yatọ si i afi irun ti a ki ni mọsalasi abeewọ”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ti ẹnikẹni ninu yin ba wọ masalaasi, ki o yaa ki rakaa meji siwaju ki o to jokoo
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ti ẹnikẹni ninu yin ba fẹ wọ masalaasi ki o yaa sọ pe: Allāhummo iftah li abwaaba rahmotika, ti o ba si tun jade ki o sọ pe: Allāhummo inni as’aluka min fadlika
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Irẹ Bilal, gbe irun duro, fun wa ni ìsinmi pẹlu rẹ”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹyin ènìyàn, dajudaju mo ṣe eyi ki ẹ le tẹle mi ki ẹ si le kọ́ irun kiki mi”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ti ẹ ba ti fẹ kirun, ẹ gbe saafu yin dìde, lẹyin naa ki ẹnikan ninu yin ṣe imaamu fun yín, ti o ba ti kabara, ki ẹyin naa kabara
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Mo fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, dajudaju emi ni irun mi jọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ju ninu yin, eleyii si ni irun rẹ titi o fi fi aye silẹ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Ẹni ti o buru julọ ninu awọn eniyan ni ti ole jija, ni ẹni ti o n ja irun rẹ lole” o sọ pe: Bawo ni o ṣe maa ja irun rẹ lole? O sọ pe: “ Ko nii rukuu dáadáa, ko si nii ṣe iforikanlẹ rẹ laṣẹpe”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba gbe ẹyin rẹ dide lati rukuu, o maa sọ pé: “Sami’alloohu liman hamidaHu
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n sọ lẹyin gbogbo irun ọran-anyan pe
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n sọ laaarin iforikanlẹ mejeeji pé: Robbi igfir liy, Robbi igfir liy”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Iyẹn ni Shaitan kan ti wọn n pe ni Khinzab, ti o ba ti fura mọ ọn, ki o wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro lọdọ rẹ, fẹ atẹgun si ẹgbẹ osi rẹ lẹẹmẹta
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ti Ramadan ba ti de ki o yaa ṣe umurah; tori pe dajudaju umurah inu rẹ ṣe deedee hajj
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, a n ri pe jihad (ijagun si oju-ọna Ọlọhun) ni iṣẹ ti o lọla julọ, ṣe aa nii jagun ni? O sọ pe: «Rara, ṣugbọn jihad (ijagun si oju-ọna Ọlọhun) ti o lọla julọ ni: hajj ti o mọ kanga (ti o jẹ atẹwọgba)
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Mo wa pẹlu Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ni o wa lọ sibi akitan ijọ kan, ti o si tọ ni iduro,
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹni ti o ba kọ oju ija si wa pẹlu ohun ìjà, ko kii ṣe ara wa
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
ẹ má ṣe bú atẹgun , yi e bá rí nkankan ti ko wù yín e sọ bayi pe: " irẹ Ọlọhun àwa n'bere òòrè ti wà lára atẹgun yí lọdọ rẹ àti oore tó wà nínú rẹ àti oore nkan ti wan pàá lasẹ, anwa idaabobo lọdọ rẹ níbi aburú afẹfẹ yí ati aburú nkan ti wa nínú rẹ ati aburú nkan ti wan pàá lasẹ,
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu