عن أبي أيوب رضي الله عنه عن النبي صلى الله عليه وسلم قال:
«مَنْ قَالَ: لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ وَحْدَهُ لَا شَرِيكَ لَهُ، لَهُ الْمُلْكُ وَلَهُ الْحَمْدُ وَهُوَ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ، عَشْرَ مِرَارٍ كَانَ كَمَنْ أَعْتَقَ أَرْبَعَةَ أَنْفُسٍ مِنْ وَلَدِ إِسْمَاعِيلَ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح مسلم: 2693]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Ayyuub- ki Ọlọhun yọnu si i- láti ọ̀dọ̀ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pé:
“Ẹni tí ó bá sọ pé: LAA ILAAHA ILLALLOOH WAHDAHUU LAA SHARIIKA LAHUU, LAHUL MULKU WALAHUL HAMDU, WA UWA ALAA KULLI SHAY'HIN KỌDIIR, ni ẹẹmẹwaao da gẹgẹ bii ẹni ti o sọ ẹrú mẹrin ninu ọmọ Ismail di olómìnira”.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Muslim - 2693]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé ẹni tí o ba sọ pe: “LAA ILAAHA ILLALLOOH WAHDAHUU LAA SHARIIKA LAHUU, LAHUL MULKU WALAHUL HAMDU, WA UWA ALAA KULLI SHAY’HIN KỌDIIR”, itumọ rẹ ni pe: Ko si ẹni ti a maa jọ́sìn fun ni ododo ayafi Ọlọhun nikan ṣoṣo tí ko ni orogun, Oun nikan si ni O ni ìjọba ti o pe, ti O si ni ẹtọ si ẹyìn pẹ̀lú ìfẹ́ ati gbigbetobi, yatọ si ẹlomiran, Olukapa si ni, nkan kan ko lee ko agara ba A. Ẹni tí ó bá pààrà asikiri nla yii ni ẹẹmẹwaa ni ojúmọ́, o maa gba irú ẹ̀san ti ẹni tí ó bá sọ ẹrú mẹ́rin di olominira ninu àwọn ọmọ Ismail ọmọ Ibrahim, ki ikẹ ati ọla maa ba àwọn méjèèjì- bá gbà, wọ́n dìídì dárúkọ àwọn ọmọ Ismail, ki ọla maa ba a; tori pe àwọn ni wọn jẹ abiyi ju àwọn mìíràn lọ.