عن عائشة رضي الله عنها قالت: قال النبي صلى الله عليه وسلم:
«لَا تَسُبُّوا الْأَمْوَاتَ، فَإِنَّهُمْ قَدْ أَفْضَوْا إِلَى مَا قَدَّمُوا».
[صحيح] - [رواه البخاري] - [صحيح البخاري: 1393]
المزيــد ...
Láti ọ̀dọ̀ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Ẹ ma bu àwọn òkú; torí pé wọn lọ ba nǹkan ti wọn ti síwájú”
[O ni alaafia] - [Bukhaariy gba a wa] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 1393]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe ki a ma maa bú àwọn òkú, ati pe eyi wa ninu awọn iwa buruku; torí pé wọn ti de ibi ti nǹkan ti wọn ti síwájú wa ninu iṣẹ rere tabi buruku, gẹgẹ bi o ṣe jẹ́ pé èébú yii ko lee dé ọdọ wọn, o kan maa kó sùtá ba àwọn alààyè ni.