عن جُبَير بن مُطْعِم رضي الله عنه أنه سمع النبي صلى الله عليه وسلم يقول:
«لَا يَدْخُلُ الْجَنَّةَ قَاطِعُ رَحِمٍ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح مسلم: 2556]
المزيــد ...

Láti ọ̀dọ̀ Jubair ọmọ Mut'him- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe oun gbọ ti Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe:
“Ẹni tí ba n ja okùn ẹbí ko nii wọ alujanna”.

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Muslim - 2556]

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe ẹni ti o ba gé ẹ̀tọ́ ti o jẹ dandan fun awọn ẹbí rẹ ti ko ṣe e fun wọn, tabi ti o fi suta kan wọn, tabi ti o ṣe aburu si wọn, o ni ẹtọ si ki o ma wọ alujanna.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Jija okun ẹbí jẹ ọkan ninu awọn ẹṣẹ ńlá.
  2. Dída ẹbí pọ̀ maa wa ni ibamu si àṣà ni, o maa yatọ ni aaye kan si aaye kan, ati asiko kan si asiko kan, ati awọn èèyàn kan si awọn èèyàn kan.
  3. A maa n da ẹbí pọ pẹ̀lú ṣíṣe abẹwo, ati sàárà, ati ṣíṣe dáadáa si wọn, ati bibẹ aláìsàn wo, ati pipa wọn láṣẹ ṣíṣe dáadáa, ati kikọ fun wọn kuro nibi aburú, ati nǹkan ti o yatọ si ìyẹn.
  4. Bi ẹbí tí èèyàn já okùn rẹ ba ṣe sunmọ sí ni ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ṣe maa lágbára tó.
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Èdè: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Àlékún (66)