+ -

عَنْ جَابِرِ بْنِ عَبْدِ اللهِ رضي الله عنهما أَنَّ رَسُولَ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«اتَّقُوا الظُّلْمَ، فَإِنَّ الظُّلْمَ ظُلُمَاتٌ يَوْمَ الْقِيَامَةِ، وَاتَّقُوا الشُّحَّ، فَإِنَّ الشُّحَّ أَهْلَكَ مَنْ كَانَ قَبْلَكُمْ، حَمَلَهُمْ عَلَى أَنْ سَفَكُوا دِمَاءَهُمْ وَاسْتَحَلُّوا مَحَارِمَهُمْ».

[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 2578]
المزيــد ...

Lati ọdọ Jaabir ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:
"Ẹ paya abosi, nitori pe abosi jẹ awọn okunkun ni ọjọ igbedide, ẹ paya ahun, nitori pe ahun lo pa awọn ti wọn ṣáájú yin run, o ti wọn lati maa ta awọn ẹjẹ wọn silẹ wọn si sọ awọn eewọ wọn di ẹtọ"

[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 2578]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣekilọ kuro nibi abosi, ninu rẹ ni: Ṣíṣe abosi awọn eniyan ati abosi ara ẹni ati ṣíṣe abosi nibi iwọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, Oun ni gbigbe funfun ẹni ti o ni ẹtọ ni ẹtọ rẹ ju silẹ, ati pe ṣíṣe abosi jẹ okunkun fun awọn ti wọn n ṣe e ni ọjọ igbedide latara ṣiṣẹlẹ awọn ile koko ati awọn ibẹru, O tun kọ kuro nibi ash-shuhhu, oun ni eyi ti o le koko ninu ahun pẹlu ojúkòkòrò, ninu rẹ ni aṣeeto nibi pipe awọn iwọ ti owo ati ilekoko ojúkòkòrò lori aye, Ati pe iran yii ninu abosi ti pa awọn ti wọn ṣíwájú wa run ninu awọn ijọ, nigba ti o ti wọn lọ sibi pipa awọn kan ninu wọn, ati ṣíṣe nnkan ti Ọlọhun ṣe leewọ ninu awọn nnkan eewọ lẹtọọ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Nina owo ati biba awọn ọmọ iya kẹ́dùn wa ninu awọn okunfa ini ifẹ ara ẹni ati irẹpọ.
  2. Ahun ati apọju ahun maa n ti ẹni lọ sibi ìyapa ati awọn ibajẹ ati ẹṣẹ.
  3. Ìwòye si awọn isẹsi awọn ijọ ìṣáájú.