عن أبي هريرة رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«أَكْمَلُ الْمُؤْمِنِينَ إِيمَانًا أَحْسَنُهُمْ خُلُقًا، وَخَيْرُكُمْ خَيْرُكُمْ لِنِسَائِهِمْ».
[حسن] - [رواه أبو داود والترمذي وأحمد] - [سنن الترمذي: 1162]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Mumini ti o pe jù ni igbagbọ ni ẹni tí ìwà rẹ dara ju, ẹni tí ó loore ju ninu yin ni ẹni tí o dara ju fun awọn obinrin wọn”.
[O daa] - [Abu Daud ati Tirmiziy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa] - [Sunanu ti Tirmidhiy - 1162]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé èèyàn ti o pe julọ ni igbagbọ ni ẹni tí ìwà rẹ dáa, bíi títú ojú ká, ati ṣíṣe dáadáa, ati ọ̀rọ̀ rere, ati ki èèyàn má fi sùtá kan ẹlòmíràn.
Mumini ti o loore julọ ni àwọn ti wọn loore julọ fun awọn obinrin wọn, gẹgẹ bii ìyàwó rẹ, ati awọn ọmọbìnrin rẹ, ati awọn arábìnrin rẹ, ati awọn mọlẹbi rẹ lóbìnrin; torí pé àwọn ni wọn ni ẹtọ si iwa dáadáa ju ninu awọn èèyàn.