عن جابر رضي الله عنه أن رسول الله صلى الله عليه وسلم قال:
«رَحِمَ اللهُ رَجُلًا سَمْحًا إِذَا بَاعَ، وَإِذَا اشْتَرَى، وَإِذَا اقْتَضَى».
[صحيح] - [رواه البخاري] - [صحيح البخاري: 2076]
المزيــد ...
Lati ọdọ Jabir - ki Ọlọhun yọnu si i - ó ní dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pé:
"Ikẹ Ọlọhun kó maa bá ọkunrin kan tí ó maa n ṣe ìrọ̀rùn fúnni nígbà ti ó bá tajà, ati nigba ti ó bá rajà, ati nigba ti ó bá fẹ́ gba gbèsè".
[O ni alaafia] - [Bukhaariy gba a wa] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 2076]
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe adura ikẹ fun gbogbo ẹniti ó bá jẹ́ onírọ̀rùn, ti o sì jẹ́ ọlọ́rẹ nibi ọja rẹ̀; kò nii lekoko mọ oluraja nibi iye owo ọja, yoo sì maa ba a lo pọ̀ pẹlu ìwà daadaa, tí ó jẹ́ onírọ̀rùn ati ọlọ́rẹ nigba ti o bá rajà; nítorí náà ko nii ṣe àbòsí ki o wa dín iye owó ọjà kù. tí ó jẹ́ onírọ̀rùn ati ọlọ́rẹ nigba ti o bá lọ sin awọn gbese tí ẹlomiran jẹ ẹ; ko nii lekoko mọ tálákà tabi aláìní, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ó maa fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ati aanu sin gbese lọwọ wọn ni, ó sì maa lọ́ aláìní lara titi o fi maa ri gbese san.