عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه عَنِ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«رَغِمَ أَنْفُ، ثُمَّ رَغِمَ أَنْفُ، ثُمَّ رَغِمَ أَنْفُ»، قِيلَ: مَنْ؟ يَا رَسُولَ اللهِ قَالَ: «مَنْ أَدْرَكَ أَبَوَيْهِ عِنْدَ الْكِبَرِ، أَحَدَهُمَا أَوْ كِلَيْهِمَا فَلَمْ يَدْخُلِ الْجَنَّةَ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 2551]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:
"Imu kan gbolẹ, Imu kan gbolẹ, Imu kan gbolẹ", wọn sọ pé: Tani? Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, o sọ pe: "Ẹni ti o ba obi rẹ mejeeji nigba ogbo, ọkan ninu awọn mejeeji tabi awọn mejeeji ti ko wa wọ alujanna".
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 2551]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- tọrọ iyẹpẹrẹ ati idojuti titi o fi da gẹgẹ bii pe o ki imu rẹ bọ inu erupẹ- o paara rẹ lẹẹmẹta- wọn wa bi i leere pé: Tani ẹni yii irẹ ojiṣẹ Ọlọhun ti o ṣepe fún?
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: Ẹni ti o ba awọn obi rẹ mejeeji nigba ogbo- ọkan ninu awọn mejeeji tabi awọn mejeeji-, ti wọn ko wa jẹ okunfa wiwọ alujanna rẹ; ìyẹn maa ri bẹẹ torí aiṣe daadaa si awọn mejeeji ati ṣiṣẹ awọn mejeeji.