+ -

عن أبي أيوب الأنصاري رضي الله عنه أن رسول الله صلى الله عليه وسلم قال:
«لَا يَحِلُّ لِرَجُلٍ أَنْ يَهْجُرَ أَخَاهُ فَوْقَ ثَلَاثِ لَيَالٍ، يَلْتَقِيَانِ، فَيُعْرِضُ هَذَا وَيُعْرِضُ هَذَا، وَخَيْرُهُمَا الَّذِي يَبْدَأُ بِالسَّلَامِ».

[صحيح] - [متفق عليه]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Ayyub Al-Ansaariy- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
"c2">“Kò tọ́ fun ọmọniyan ki o yan ọmọ-ìyá rẹ lódì tayọ ọjọ́ mẹ́ta, àwọn méjèèjì maa pàdé, eléyìí maa wa gbúnrí, èyí naa maa gbúnrí, ẹni tí ó ni oore ju ninu awọn mejeeji ni ẹni tí ó bá kọ́kọ́ sálámọ̀”.

O ni alaafia - Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ ki Mùsùlùmí yan ọmọ-ìyá rẹ ti o jẹ Mùsùlùmí lodi kọjá ọjọ́ mẹ́ta, ti wọn maa pade ara wọn, ti wọn ko nii kí ara wọn, wọn ko si nii ba ara wọn sọ̀rọ̀.
Ẹni tí ó ni ọlá ju ninu awọn mejeeji ti wọn n jà yii ni ẹni tí o ba n gbìyànjú lati mu odì kúrò, ti o maa wa kọ́kọ́ salamọ, ohun tí a gba lero pẹ̀lú HAJRU nibi ni odì nítorí ìpín ti ẹmi, ṣùgbọ́n odì nítorí tí Ọlọhun, gẹgẹ bii yiyan àwọn ẹlẹṣẹ lódì, ati awọn oni adadaalẹ, ati awọn ọrẹ burúkú, eléyìí ko ni asiko, bi ko ṣe pe o nii ṣe pẹ̀lú anfaani nibi odì, ti o si maa kúrò pẹ̀lú kikuro rẹ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣíṣe odì ni ẹtọ fun ọjọ mẹta tabi ki o ma to bẹẹ, fun ti adamọ ti ọmọniyan, wọn wa yọnda odì fun ọjọ mẹta ki nǹkan ti o ṣẹri wa yẹn le lọ.
  2. Ọla ti n bẹ fun salamọ, ati pe o maa mu ohun ti n bẹ ninu ẹmi kúrò, o si tun jẹ àmì fun ìfẹ́.
  3. Ojúkòkòrò Isilaamu lori ijẹ ọmọ-iya ati ifẹ láàrin àwọn Musulumi.