عن أبي موسى رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«إِنَّ اللهَ لَيُمْلِي لِلظَّالِمِ، حَتَّى إِذَا أَخَذَهُ لَمْ يُفْلِتْهُ» قَالَ: ثُمَّ قَرَأَ: «{وَكَذَلِكَ أَخْذُ رَبِّكَ إِذَا أَخَذَ الْقُرَى وَهِيَ ظَالِمَةٌ إِنَّ أَخْذَهُ أَلِيمٌ شَدِيدٌ}[هود: 102]»
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 4686]
المزيــد ...
Láti ọ̀dọ̀ Abu Musa- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Dájúdájú Ọlọhun maa n lọ́ alabosi lára, titi ti yoo fi mu u ti ko si nii jẹ ki ó bọ́”, o sọ pe: Lẹ́yìn náà ni o ka: “{Báyẹn ni ìgbámú Olúwa rẹ. Nígbà tí Ó bá gbá àwọn ìlú alábòsí mú, dájúdájú Ó máa gbá a mú pẹ̀lú ìyà ẹlẹ́ta-eléro t’ó le} [Huud: 102]”
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 4686]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣọ wa lara kúrò nibi itẹsiwaju ninu abosi dídá ẹṣẹ ati ṣíṣe ẹbọ, ati ṣíṣe abosi fun awọn èèyàn nibi ẹ̀tọ́ wọn; torí pé Ọlọhun maa n lọ alabosi lára, O si maa n jẹ ki ẹmi rẹ o gùn ti dúkìá rẹ si tun maa pọ̀, ko waa ni kanju fi ìyà jẹ ẹ, ti ko ba wa ronupiwada, O maa mu u ti ko si nii fi i sílẹ̀ fun abosi rẹ ti o pọ.
Lẹ́yìn naa ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ka: {Báyẹn ni ìgbámú Olúwa rẹ. Nígbà tí Ó bá gbá àwọn ìlú alábòsí mú, dájúdájú Ó máa gbá a mú pẹ̀lú ìyà ẹlẹ́ta-eléro t’ó le} [Huud: 102].