+ -

عن أبي هريرة رضي الله عنه: أن رسول الله صلى الله عليه وسلم قال:
«يَنْزِلُ رَبُّنَا تَبَارَكَ وَتَعَالَى كُلَّ لَيْلَةٍ إِلَى السَّمَاءِ الدُّنْيَا حِينَ يَبْقَى ثُلُثُ اللَّيْلِ الْآخِرُ، يَقُولُ: «مَنْ يَدْعُونِي فَأَسْتَجِيبَ لَهُ؟ مَنْ يَسْأَلُنِي فَأُعْطِيَهُ؟ مَنْ يَسْتَغْفِرُنِي فَأَغْفِرَ لَهُ؟».

[صحيح] - [متفق عليه]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Hurayra – ki Ọlọhun yọnu si i– dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe:
«Oluwa wa ti ọla Rẹ ga maa n sọkalẹ ni gbogbo oru si sanmọ aye nigba ti o ba ṣẹku idamẹta igbẹyin, yio wa maa sọ pe: «Tani yio pe Mi ki n maa da a lohun? Tani yio bi Mi leere ki n si maa fun un? Tani yio wa aforijin Mi ki n si ṣe aforijin fun un?».

O ni alaafia - Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni

Àlàyé

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju Ọlọhun ti ọla Rẹ ga maa n sọkalẹ ni gbogbo oru si sanmọ aye nigba ti o ba ku idamẹta igbẹyin ninu oru, O si tun n ṣe awọn ẹru Rẹ ni ojukokoro ki wọn o pe E, pe Oun yio jẹ ipe ẹni ti o ba pe Oun, O si tun ṣe wọn ni oju ọyin ki wọn o bi I leere nkan ti wọn n fẹ, pe Oun yio fun ẹni ti o ba bi Oun leere, O si tun pe wọn sibi ki wọn wa aforijin Rẹ nibi awọn ẹṣẹ wọn pe Oun maa n ṣe aforijin fun awọn ẹru Oun ti wọn jẹ olugbagbọ ododo.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ọla ti n bẹ fun idamẹta ti o gbẹyin ni oru ati irun kiki ati adua ṣiṣe ati wiwa aforijin ninu rẹ.
  2. O tọ fun Musulumi nigba ti o ba gbọ hadiisi yii ki o pọ ni ojúkòkòrò lori lilo awọn asiko gbigba adua.
Àlékún