+ -

عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه قال: قال رَسُولُ الله صلى الله عليه وسلم:
«إِنَّ اللهَ يَغَارُ، وَإِنَّ الْمُؤْمِنَ يَغَارُ، وَغَيْرَةُ اللهِ أَنْ يَأْتِيَ الْمُؤْمِنُ مَا حَرَّمَ عَلَيْهِ».

[صحيح] - [متفق عليه]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
"Dajudaju Ọlọhun maa n jowu, ati pe dajudaju olugbagbọ naa maa n jowu, owu jijẹ Ọlọhun ni ki olugbagbọ maa ṣe nnkan ti Ọlọhun ṣe ni eewọ fun".

O ni alaafia - Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju Ọlọhun maa n jowu, O si maa n binu O si maa n korira, gẹgẹ bi olugbagbọ naa ṣe maa n jowu, ti o si maa n binu, ti o si maa n korira, ati pe okunfa jijowu Ọlọhun ni ki olugbagbọ ṣe nnkan ti O ṣe ni eewọ ninu iwa ibajẹ gẹgẹ bii ṣìná ati ki ọkùnrin maa ba ọkùnrin lò pọ̀, ati ole jija ati ọti mimu, ati eyi ti o yàtọ̀ si wọn ninu awọn iwa ibajẹ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ikilọ kuro nibi ibinu Ọlọhun ati ifiyajẹni Rẹ nigba ti wọn ba fa ọgba awọn eewọ Rẹ ya.
Àlékún