عن أبي هريرة رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«إِنَّ اللهَ لَا يَنْظُرُ إِلَى صُوَرِكُمْ وَأَمْوَالِكُمْ، وَلَكِنْ يَنْظُرُ إِلَى قُلُوبِكُمْ وَأَعْمَالِكُمْ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 2564]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Dájúdájú Ọlọhun ko nii wo àwòrán yin ati dúkìá yin, ṣùgbọ́n O maa wo ọkàn yin ati iṣẹ yin”.
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 2564]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ko nii wo àwòrán ẹrú ati ara wọn, boya o rẹwà ni abi o burẹ́wà? Boya o tobi ni abi o kéré? Bóyá o ni alaafia ni abi o n ṣe àìsàn? Ko si nii wo dúkìá wọn, bóyá o pọ ni abi o kéré? Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn ko nii fi àwọn nǹkan wọ̀nyí bi àwọn ẹrú Rẹ, ko si nii ṣe ìṣirò wọn lórí rẹ ati bi wọn ṣe yatọ si ara wọn nínú ẹ, ṣùgbọ́n O maa wo ọkàn wọn ati nǹkan ti o wa ninu ẹ bii ipaya ati àmọ̀dájú, ati ododo ati imọkanga, tabi gbigbero ṣekarimi ati ṣekagbọmi, O si tun maa wo iṣẹ wọn bóyá o dára ni abi ko dára, O maa wa sẹsan lori ẹ.