+ -

عن أبي هريرة رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«قال الله تبارك وتعالى: أنا أغنى الشركاء عن الشرك، من عمل عملًا أشرك فيه معي غيري، تركتُهُ وشركَهُ».

[صحيح] - [رواه مسلم]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, sọ pe:
“Ọlọhun, Oníbùkún ti O ga jùlọ, sọ pe: Èmi ni Olùrọrọ̀ julọ tayọ níní orogún. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ kan, ti o mu orogun ninu rẹ̀ pẹlu Èmi Ọlọhun, Emi yóò fi òun àti orogun rẹ̀ sílẹ̀.

O ni alaafia - Muslim gba a wa

Àlàyé

Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, n fun wa ni iro pe: Ọlọhun, Onibukun ti O ga julọ sọ pe: Òun ni Olùrọrọ̀ julọ tayọ níní orogún, Òun ni Ẹni tí Ó rọrọ̀ tayọ gbogbo nkan, ati pe ti eniyan bá ṣe iṣẹ ijọsin kan, ti o sì ṣe e fun Ọlọhun ati ohun miiran tó yatọ si Ọlọhun; Ọlọ́hun yoo gbe e ju sílẹ̀, kò nii gbà á lọ́wọ́ rẹ̀, yoo sì dá a padà fún un. Nitori naa, ọranyan ni ki iṣẹ́ jẹ́ mimọ fun Ọlọ́hun Ọba Aleke ọla, nítorí pé, Ọlọ́hun – mimọ fun Un – kò nii gba iṣẹ kan ayafi eyiti ó jẹ́ mimọ lati lè fi ri ojú rere Rẹ̀.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Tajikistan
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ìkìlọ̀ kuro nibi ẹbọ pẹlu gbogbo awọn ọna rẹ; ati pe o jẹ ìkọdí fún itẹwọgba iṣẹ ijọsin lọdọ Ọlọhun.
  2. Níní ìmọ̀lára ọrọ̀ Ọlọhun ati titobi Rẹ̀, ó wà ninu awọn nkan tó máa n ṣe iranlọwọ lati jẹ ki a ṣe iṣẹ ní mimọ fun Ọlọhun.