+ -

عَنِ النُّعْمَانِ بْنِ بَشِيرٍ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُمَا عَنِ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«مَثَلُ القَائِمِ عَلَى حُدُودِ اللَّهِ وَالوَاقِعِ فِيهَا، كَمَثَلِ قَوْمٍ اسْتَهَمُوا عَلَى سَفِينَةٍ، فَأَصَابَ بَعْضُهُمْ أَعْلاَهَا وَبَعْضُهُمْ أَسْفَلَهَا، فَكَانَ الَّذِينَ فِي أَسْفَلِهَا إِذَا اسْتَقَوْا مِنَ المَاءِ مَرُّوا عَلَى مَنْ فَوْقَهُمْ، فَقَالُوا: لَوْ أَنَّا خَرَقْنَا فِي نَصِيبِنَا خَرْقًا وَلَمْ نُؤْذِ مَنْ فَوْقَنَا، فَإِنْ يَتْرُكُوهُمْ وَمَا أَرَادُوا هَلَكُوا جَمِيعًا، وَإِنْ أَخَذُوا عَلَى أَيْدِيهِمْ نَجَوْا، وَنَجَوْا جَمِيعًا».

[صحيح] - [رواه البخاري]
المزيــد ...

Lati ọdọ An-Nu‘maan ọmọ Basheer - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - lati ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe:
«Apejuwe ẹni ti o duro nibi aala Ọlọhun ati ẹni ti o ko sinu rẹ, da gẹgẹ bi apejuwe awọn ijọ kan ti wọn mu aje lori ọkọ oju-omi, ni apakan wọn wa bọ si oke rẹ ti apakan wọn si wa ni isalẹ rẹ, ti awọn ti wọn wa ni isalẹ rẹ ba ti wa fẹ bu omi mu wọn yio gba ọdọ awọn ti wọn wa l'oke wọn kọja, ni wọn wa sọ pe: Ao ba si lu iho kan si ọdọ wa ki a ma fi fi ṣuta kan awọn ti wọn wa ni oke wa, ti wọn ba fi wọn silẹ pẹlu nkan ti wọn gbero gbogbo wọn maa parun, ti wọn ba wa gba wọn ni ọwọ mu (ti wọn kọ fun wọn) wọn o la (iyẹn awọn ti wọn gbero lati lu iho), ati pe gbogbo wọn pata ni yio la».

O ni alaafia - Bukhaariy gba a wa

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - fi apẹrẹ le'lẹ fun awọn ti wọn duro nibi aala Ọlọhun, awọn ti wọn duro deede lori aṣẹ Ọlọhun, awọn ti wọn n pàṣẹ daadaa, awọn ti wọn n kọ ibajẹ, Ati pe apejuwe awọn ti wọn ko sinu awọn aala Ọlọhun ti wọn n fi daadaa silẹ, ti wọn n wu iwa ibajẹ, ati oripa iyẹn nibi lila awujọ, da bi apejuwe ijọ kan ti wọn gun ọkọ oju-omi, ni wọn wa mu aje lati mọ awọn ti wọn maa jokoo si oke ọkọ oju-omi ati awọn ti wọn maa jokoo si isalẹ rẹ, ni awọn kan wa wa ni oke rẹ, ti awọn kan si wa ni isalẹ rẹ, ti awọn ti wọn wa ni isalẹ ba wa fẹ pọn omi wọn a lọ si ọdọ awọn ti wọn wa ni oke wọn, Ni awọn ti wọn wa ni isalẹ wa sọ pe: Ti awa ba le lu oju kan ni aaye wa ni isalẹ ti a maa ti ibẹ mumi, ki a ma baa maa ni awọn ti wọn wa ni oke wa lara, ti awọn to wa l'oke ba fi wọn silẹ lati ṣe nkan yẹn, ọkọ oju-omi yẹn a tẹ gbogbo wọn ri, ṣugbọn ti wọn ba dide lati kọ fun wọn nibi iyẹn, awọn ijọ mejeeji ni yio la papọ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Dari Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Pataki pipaṣẹ daadaa ati kikọ kuro nibi aidaa nibi dida aabo bo awọn awujọ ati lila rẹ.
  2. Ninu awọn ọna ikọnilẹkọọ ni fifi àkàwé lelẹ, lati fi sun àwọn itumọ mọ ọpọlọ pẹlu aworan ti oju leri.
  3. Ṣiṣe ibajẹ ti o han pẹlu aikọ kuro nibẹ, aburu ni ti yio mu inira ba gbogboogbo.
  4. Iparun awujọ n bẹ nibi fifi awọn onibajẹ silẹ ki wọn o maa tan ibajẹ ka orilẹ.
  5. Ìwà ti kò tọ̀nà ati aniyan daadaa ko to fun didara iṣẹ.
  6. Ojúṣe ninu àwùjọ Musulumi, ohun apawọpọṣe ni, kii ṣe ohun ti ẹnìkan maa dá ṣe.
  7. Fifi iya jẹ gbogboogbo pẹlu awọn ẹsẹ awọn kan nigba ti wọn o ba ti ṣe atako.
  8. Awọn onibajẹ maa n fi ibajẹ wọn han ni aworan daadaa ni awujọ gẹgẹ bi awọn munaafiki ṣe rí.
Àlékún