عن أبي هريرة رضي الله عنه عن النبي صلى الله عليه وسلم:
«اللهُمَّ لَا تَجْعَلْ قَبْرِي وَثَنًا، لَعَنَ اللهُ قَوْمًا اتَّخَذُوا قُبُورَ أَنْبِيَائِهِمْ مَسَاجِدَ».
[صحيح] - [رواه أحمد] - [مسند أحمد: 7358]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, ó gba a wá lati ọdọ Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a:
“Ọlọhun, má ṣe sọ saare mi di òrìṣà, Ọlọhun ti ṣẹbi lé awọn ijọ kan tí wọ́n sọ saare awọn Anabi wọn di mọṣalaṣi”.
[O ni alaafia] - [Ahmad ni o gba a wa] - [Musnad ti Ahmad - 7358]
Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, képe Oluwa rẹ̀ pé kí o má ṣe sọ saare oun dà gẹ́gẹ́ bí oriṣa ti awọn eniyan n sìn nipa gbigbe titobi fun un ati fífi orí kanlẹ fun un. Lẹhin naa, Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, fún wa ní ìró pé Ọlọhun ti gbe ikẹ Rẹ̀ jìnnà sí awọn tí wọ́n sọ saare awọn Anabi di mọṣalaṣi; nitori sísọ ọ di mọṣalaṣi lè di ọna awawi lati jọsin fún wọn, ati níní adiọkan sí wọn.