+ -

عن بعض أزواج النبي صلى الله عليه وسلم عن النبي صلى الله عليه وسلم قال:
«مَنْ أَتَى عَرَّافًا فَسَأَلَهُ عَنْ شَيْءٍ لَمْ تُقْبَلْ لَهُ صَلَاةٌ أَرْبَعِينَ لَيْلَةً».

[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 2230]
المزيــد ...

Lati ọdọ àwọn kan ninu awọn ìyàwó Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:
“Ẹni ti o ba lọ ba yẹmiwo kan ti o wa bi i leere nipa nnkan kan, wọn ko nii gba irun rẹ fun ogoji ọjọ”.

[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 2230]

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣọ wa lara kuro nibi lílọ bá adagbigba- orúkọ kan ni ti o kárí fun yẹmiwo, ati awòràwọ̀, ati ẹni ti n tẹ yanrìn, ati bẹẹ bẹẹ lọ, ninu awọn ti maa n mu ẹri wa fun mímọ kọ̀kọ̀ pẹ̀lú àwọn itisiwaju kan ti o maa n lò- ati pe ọ̀wọ́ọ pe èèyàn kan bi i leere nipa nǹkan kan ninu kọ̀kọ̀, Ọlọhun ko nii fun un ni ẹsan ìrun rẹ fun ogójì ọjọ́; ki ìyẹn le maa jẹ ìyà fun un lórí ẹṣẹ ńlá yìí.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف البلغارية Ti ede Azerbaijan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣíṣe iṣẹ yẹmiwo ni eewọ, ati lílọ ba àwọn yẹmiwo, ati bibi wọn nipa kọ̀kọ̀.
  2. Èèyàn lè má gba ẹ̀san itẹle àṣẹ Ọlọhun ki o le jẹ ìjìyà fun un lórí ẹṣẹ.
  3. O maa ko sinu hadiisi naa nǹkan ti a n pe ni ìràwọ̀ ati wiwo o, ati kíkà àtẹ́lẹwọ́ àti ife-ìmumi- kódà ki èèyàn kan fẹ mọ̀ nipa rẹ lásán-; torí pé gbogbo ìyẹn wa ninu iṣẹ yẹmiwo ati pípe apemọra ìní-ìmọ̀ kọ̀kọ̀.
  4. Ti eyi ba jẹ ẹsan ẹni tí ó lọ ba yẹmiwo, bawo wa ni ẹsan yẹmiwo gan fúnra rẹ ṣe maa ri?
  5. Ìrun ogójì ọjọ́ yẹn maa tó o, kii ṣe dandan fun un ki o da a pada, ṣùgbọ́n ko nii gba ẹsan rẹ.