عن ابن عباس رضي الله عنهما قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«من اقتبَسَ علْمًا مِنَ النُّجُومِ اقْتبَسَ شُعبَة مِن السِّحرِ، زادَ ما زادَ».
[صحيح] - [رواه أبو داود وابن ماجه وأحمد] - [سنن أبي داود: 3905]
المزيــد ...
Lati ọdọ ọmọ Abbaas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Ẹni tí ó bá gba ìmọ̀ latara ìràwọ̀, onítọ̀hún ti gba ẹka kan ninu oògùn, bi o ba ṣe n lekun ninu imọ ìràwọ̀ naa ni kikọ oògùn rẹ naa ṣe maa lékún”.
[O ni alaafia] - [Abu Daud ati Ibnu Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a wa] - [Sunanu ti Abu Daud - 3905]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe ẹni ti o ba kọ́ imọ ìràwọ̀, ati fifi lílọ-bíbọ̀ rẹ, ati ìwọlé rẹ, ati ìjáde rẹ ṣe itọka si awọn ìṣẹ̀lẹ̀ orí ilẹ̀, bii ikú lagbaja, tabi iṣẹmi rẹ, tàbí àìsàn rẹ, ati nǹkan ti o jọ ìyẹn ninu nnkan ti o maa ṣẹlẹ̀ ni ọjọ́ iwájú, onítọ̀hún ti kọ́ ẹ̀yà kan ninu oògùn, bi èèyàn ba ṣe n kọ́ ọ sí naa ni yoo ṣe maa pọ̀ ni oògùn sí.