عن عقبة بن عامر رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«أَحَقُّ الشُّرُوطِ أَنْ تُوفُوا بِهِ مَا اسْتَحْلَلْتُمْ بِهِ الْفُرُوجَ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 2721]
المزيــد ...

Lati ọdọ ‘Uqbah ọmọ ‘Aamir- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
”Eyi ti o lẹtọọ julọ ninu awọn majẹmu lati mu ṣẹ ni nnkan ti ẹ fi sọ awọn abẹ di ẹtọ”.

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 2721]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe dajudaju eyi ti o lẹtọọ julọ ninu awọn majẹmu lati mú ṣẹ ni nnkan ti o jẹ okunfa nibi sisọ igbadun pẹlu obinrin di ẹtọ, awọn ni awọn majẹmu ti o lẹtọọ ti iyawo maa n beere fun wọn nibi siso yigi.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Jijẹ dandan mimu awọn majẹmu ṣẹ ti ọkan ninu ọkọ ati iyawo ṣe ni dandan fun ara wọn, afi majẹmu kan ti o ṣe ẹtọ ni eewọ tabi ṣe eewọ lẹtọọ.
  2. Mimu awọn majẹmu yigi ṣẹ jẹ nnkan ti o kanpa ju nnkan ti o yatọ si wọn lọ; nitori pe o jẹ ìjìrọ̀ fun sisọ awọn abẹ di ẹtọ.
  3. Titobi ipo igbeyawo ninu Isilaamu, latari bi o ṣe kanpá mọ́ mimu awọn majẹmu rẹ ṣẹ.
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Èdè: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Àlékún (63)