عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي لله عنه قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«لَا يَفْرَكْ مُؤْمِنٌ مُؤْمِنَةً، إِنْ كَرِهَ مِنْهَا خُلُقًا رَضِيَ مِنْهَا آخَرَ» أَوْ قَالَ: «غَيْرَهُ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 1469]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:
«Mumini o gbọdọ maa korira muminah, ti o ba korira iwa kan lara rẹ, yio yọnu si omiran lara rẹ» tabi o sọ pe: «Yatọ si i».
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 1469]
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kọ fun ọkọ ki o maa korira iyawo rẹ ni ikorira ti yio ti i debi ki o maa ṣe abosi rẹ ati ki o pa a ti ati ki o ma ya si i; nitori pe dajudaju ọmọniyan wọn da a mọ aipe ni, ti o ba wa korira iwa buruku kan ni ara rẹ, yio ri iwa miran ti o daa; nitori naa yio yọnu si èyí tí o daa ti o ṣe deede, ki o si ṣe suuru lori èyí tí ko daa ti ko yọnu si, èyí tí yio mu un ṣe suuru ti ko si nii korira rẹ ni ikorira ti yio gbe e lọ s'ibi kikọ ọ.