+ -

عَنِ ابْنِ عُمَرَ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُمَا قَالَ:
حَفِظْتُ مِنَ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ عَشْرَ رَكَعَاتٍ: رَكْعَتَيْنِ قَبْلَ الظُّهْرِ، وَرَكْعَتَيْنِ بَعْدَهَا، وَرَكْعَتَيْنِ بَعْدَ المَغْرِبِ فِي بَيْتِهِ، وَرَكْعَتَيْنِ بَعْدَ العِشَاءِ فِي بَيْتِهِ، وَرَكْعَتَيْنِ قَبْلَ صَلاَةِ الصُّبْحِ، وَكَانَتْ سَاعَةً لاَ يُدْخَلُ عَلَى النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ فِيهَا، حَدَّثَتْنِي حَفْصَةُ أَنَّهُ كَانَ إِذَا أَذَّنَ المُؤَذِّنُ وَطَلَعَ الفَجْرُ صَلَّى رَكْعَتَيْنِ، وَفِي لَفْظٍ: أَنَّ النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ كَانَ يُصَلِّي بَعْدَ الْجُمُعَةِ رَكْعَتَيْنِ.

[صحيح] - [متفق عليه بجميع رواياته] - [صحيح البخاري: 1180]
المزيــد ...

Lati ọdọ ọmọ Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe:
Mo ha rakah mẹwaa lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-: Rakah meji ṣíwájú irun Zuhr, ati rakah meji lẹyin rẹ, ati rakah meji lẹyin irun Magrib ni ile rẹ, ati rakah meji lẹyin irun Ishai ni ile rẹ, ati rakah meji ṣíwájú irun Subhi; o jẹ asiko kan ti wọn ko ki n wọle ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibẹ, Hafsoh sọ fun mi pe ti oluperun ba ti pe irun ti alufajari ba si ti yọ, o maa ki rakah meji, o wa ninu ẹgbawa kan pé: Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n ki rakah meji lẹyin irun jimọh.

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni i pẹ̀lú gbogbo àwọn ẹgbawa rẹ] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 1180]

Àlàyé

Abdullahi ọmọ Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- n ṣàlàyé pe: Dajudaju ninu awọn nafila ti oun ha lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- jẹ rakah mẹwaa ti wọn pe wọn ni sunanur rawaatib, Rakah meji ṣíwájú irun Zuhr, ati rakah meji lẹyin rẹ, Ati rakah meji lẹyin irun Magrib ni ile rẹ, Ati rakah meji lẹyin irun Ishai ni ile rẹ, Ati rakah meji ṣíwájú irun alufajari, Ni rakah mẹwaa ba pe. Ṣugbọn irun Jimọh o maa n ki rakah meji lẹyin rẹ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Ede Jamani Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè Czech Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada Ti èdè ìlú Ukraine
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣíṣe awọn nafila yii ni nnkan ti a fẹ, ati didunni mọ wọn.
  2. Ṣíṣe kiki naafila ninu ile lofin.