عَنْ ‌أَبِي قَتَادَةَ السَّلَمِيِّ رضي الله عنه أَنَّ رَسُولَ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«إِذَا دَخَلَ أَحَدُكُمُ الْمَسْجِدَ فَلْيَرْكَعْ رَكْعَتَيْنِ قَبْلَ أَنْ يَجْلِسَ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 444]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Qataada as-Sulamiyy – ki Ọlọhun yọnu si i – dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe:
«Ti ẹnikẹni ninu yin ba wọ masalaasi, ki o yaa ki rakaa meji siwaju ki o to jokoo».

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 444]

Àlàyé

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe ẹni ti o ba wa si masalaasi ti o si wọle sibẹ ni eyikeyii asiko, ati fun èyíkéyìí erongba, ni ojukokoro lati ki rakaah meji siwaju ki o to jokoo, ati pe awọn mejeeji ni rakaah meji kiki masalaasi.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ninifẹẹ si kiki irun rakaa meji ni ti kiki masalaasi siwaju ijokoo.
  2. Aṣẹ yii wa fun ẹni ti o ba gbero lati jokoo, nitori naa ẹni ti o ba wọ masalaasi ti o si jade siwaju ki o to jokoo, aṣẹ yẹn o ko o sinu.
  3. Ti ẹni ti o fẹ kirun ba wọ masalaasi ti awọn eeyan si n kirun lọwọ, ti o wa darapọ mọ wọn nibẹ, ko bukaata si ki o ki rakaa meji naa mọ.
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Èdè: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Àlékún (57)