عَنْ أَبِي حُمَيْدٍ أَوْ عَنْ أَبِي أُسَيْدٍ قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«إِذَا دَخَلَ أَحَدُكُمُ الْمَسْجِدَ فَلْيَقُلِ: اللَّهُمَّ افْتَحْ لِي أَبْوَابَ رَحْمَتِكَ، وَإِذَا خَرَجَ فَلْيَقُلِ: اللَّهُمَّ إِنِّي أَسْأَلُكَ مِنْ فَضْلِكَ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 713]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Humayd tabi lati ọdọ Abu Usayd, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe:
«Ti ẹnikẹni ninu yin ba fẹ wọ masalaasi ki o yaa sọ pe: Allāhummo iftah li abwaaba rahmotika, ti o ba si tun jade ki o sọ pe: Allāhummo inni as’aluka min fadlika».
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 713]
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – tọka awọn ijọ rẹ sibi adua ti wọn maa ṣe nigba ti wọn ba fẹ wọ masalaasi: (Allāhummo iftah li abwaaba rahmotika), nigba naa ni yio beere lọwọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ki O ṣe ni irọrun fun un awọn okunfa ikẹ Rẹ, ati pe ti o ba fẹ jade ki o sọ pe: (Allāhummo inni as’aluka min fadlika), nigba naa yio waa bẹ Ọlọhun ninu ọla Rẹ ati alekun daadaa Rẹ ninu jijẹ-mimu halaali.