+ -

عن جابرٍ رضي الله عنه قال: سمعت النبي صلى الله عليه وسلم يقول:
«إِنَّ بَيْنَ الرَّجُلِ وَبَيْنَ الشِّرْكِ وَالْكُفْرِ تَرْكَ الصَّلَاةِ».

[صحيح] - [رواه مسلم]
المزيــد ...

Lati ọdọ Jaabir – ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Mo gbọ ti Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n sọ pe:
«Dajudaju nkan ti n bẹ laarin ọmọniyan ati mimu orogun mọ Ọlọhun ati ṣiṣe keferi ni gbigbe irun jù silẹ».

O ni alaafia - Muslim gba a wa

Àlàyé

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – kilọ kuro nibi gbigbe irun ọranyan ju silẹ, o si tun sọ pe dajudaju nkan ti n bẹ laarin ọmọniyan ati kiko sinu imu orogun mọ Ọlọhun ati iṣe keferi ni gbigbe irun ju silẹ, nitori naa irun ni origun keji ninu awọn origun Isilaamu, ati pe ipo rẹ tobi ninu Isilaamu, nitori naa ẹni ti o ba gbe e ju silẹ l’ẹni ti n tako ijẹ dandan rẹ o ti di keferi pẹlu apanupọ gbogbo Musulumi, ati pe ti o ba gbe e ju silẹ patapata ni ti ifi ọwọ dẹngẹrẹ mu un ati ni ti oroju, o ti di keferi, wọn si tun gba ipanupọ awọn saabe wa lori iyẹn, ti o ba wa jẹ pe o maa n fi i silẹ ni igba miran ti yio si tun ki i ni igba miran, nigba naa o ti ni ẹtọ si adehun iya to ni agbara yii.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Tọ́kì Èdè Sinhala Èdè India Èdè Vietnamese Èdè Hausa Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Burmese Thai Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Pataki irun kiki ati idunni mọ ọn, oun naa ni iyatọ laarin ṣiṣe keferi ati nini igbagbọ.
  2. Kikọ ti o le kuro nibi gbigbe irun silẹ ati rira a lare.