Ìsọ̀rí: Adisọkan .
+ -

عن أبي ذر رضي الله عنه:
عَنِ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ فِيمَا رَوَى عَنِ اللهِ تَبَارَكَ وَتَعَالَى أَنَّهُ قَالَ: «يَا عِبَادِي إِنِّي حَرَّمْتُ الظُّلْمَ عَلَى نَفْسِي، وَجَعَلْتُهُ بَيْنَكُمْ مُحَرَّمًا، فَلَا تَظَالَمُوا، يَا عِبَادِي كُلُّكُمْ ضَالٌّ إِلَّا مَنْ هَدَيْتُهُ، فَاسْتَهْدُونِي أَهْدِكُمْ، يَا عِبَادِي كُلُّكُمْ جَائِعٌ إِلَّا مَنْ أَطْعَمْتُهُ، فَاسْتَطْعِمُونِي أُطْعِمْكُمْ، يَا عِبَادِي كُلُّكُمْ عَارٍ إِلَّا مَنْ كَسَوْتُهُ، فَاسْتَكْسُونِي أَكْسُكُمْ، يَا عِبَادِي إِنَّكُمْ تُخْطِئُونَ بِاللَّيْلِ وَالنَّهَارِ وَأَنَا أَغْفِرُ الذُّنُوبَ جَمِيعًا فَاسْتَغْفِرُونِي أَغْفِرْ لَكُمْ، يَا عِبَادِي إِنَّكُمْ لَنْ تَبْلُغُوا ضَرِّي فَتَضُرُّونِي، وَلَنْ تَبْلُغُوا نَفْعِي فَتَنْفَعُونِي، يَا عِبَادِي لَوْ أَنَّ أَوَّلَكُمْ وَآخِرَكُمْ وَإِنْسَكُمْ وَجِنَّكُمْ كَانُوا عَلَى أَتْقَى قَلْبِ رَجُلٍ وَاحِدٍ مِنْكُمْ مَا زَادَ ذَلِكَ فِي مُلْكِي شَيْئًا، يَا عِبَادِي لَوْ أَنَّ أَوَّلَكُمْ وَآخِرَكُمْ وَإِنْسَكُمْ وَجِنَّكُمْ كَانُوا عَلَى أَفْجَرِ قَلْبِ رَجُلٍ وَاحِدٍ مَا نَقَصَ ذَلِكَ مِنْ مُلْكِي شَيْئًا، يَا عِبَادِي لَوْ أَنَّ أَوَّلَكُمْ وَآخِرَكُمْ وَإِنْسَكُمْ وَجِنَّكُمْ قَامُوا فِي صَعِيدٍ وَاحِدٍ فَسَأَلُونِي فَأَعْطَيْتُ كُلَّ إِنْسَانٍ مَسْأَلَتَهُ مَا نَقَصَ ذَلِكَ مِمَّا عِنْدِي إِلَّا كَمَا يَنْقُصُ الْمِخْيَطُ إِذَا أُدْخِلَ الْبَحْرَ، يَا عِبَادِي إِنَّمَا هِيَ أَعْمَالُكُمْ أُحْصِيهَا لَكُمْ ثُمَّ أُوَفِّيكُمْ إِيَّاهَا، فَمَنْ وَجَدَ خَيْرًا فَلْيَحْمَدِ اللهَ، وَمَنْ وَجَدَ غَيْرَ ذَلِكَ فَلَا يَلُومَنَّ إِلَّا نَفْسَهُ».

[صحيح] - [رواه مسلم]
المزيــد ...

Láti ọ̀dọ̀ Abu Dharr- ki Ọlọhun yọnu si i-:
Láti ọ̀dọ̀ Anọbi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- ninu ohun ti o gba wa lati ọdọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- O sọ pe: "c2">“Ẹ̀yin ẹrusin Mi, Emi ṣe abosi ni eewọ fun ara Mi, Mo si ṣe e ni eewọ laarin yin, ẹ ma ṣe abosi si ara yin, ẹ̀yin ẹrú Mi, gbogbo yin ni ẹ sọnù, ayafi ẹni tí Mo ba ṣe imọna fun; nitori naa ẹ wa imọna lọ́dọ̀ Mi, Emi yoo si ṣe amọna yin, ẹyin ẹrú Mi, ebi n pa gbogbo yin ayafi ẹni ti mo ba bọ́; nitori náà, ẹ wá oúnjẹ lọ́dọ̀ Mi, èmi yóò sì bọ́ yín. Ẹ̀yin ẹrú Mi, gbogbo yin ni ẹ wa ni ihoho ayafi eni ti Mo ba da aṣọ bo; nitori naa ẹ wa dida aṣọ bo yin lọ́dọ̀ Mi, maa da aṣọ bo yín, ẹ̀yin ẹrú Mi, ẹ n da ẹṣẹ loru ati ni ọsan, Mo si maa n ṣe aforijin àwọn ẹṣẹ pata, ki ẹ yaa wa aforijin Mi, maa forí jin yin, ẹyin ẹrú Mi, ẹ ko le de ibi ìnira Mi débi pé ẹ maa ni Mi lara, ẹ ko si lee debi anfaani Mi debi pe ẹ maa ṣe mi ni anfaani. Ẹyin ẹrusin Mi, ti ẹni akọkọ yin ati ẹni ti o kẹhin ninu yin, eniyan yin ati awọn alujannu yin, tí wọ́n ba wa lori ọkàn arákùnrin kan ti o páyà Ọlọhun jù lọ ninu yin, iyẹn ko le nǹkan kan kun ninu ọla Mi. Ẹyin ẹrusin Mi, ti ẹni akọkọ yin ati ẹni ti o kẹhin ninu yin, eniyan yin ati awọn alujannu yin, tí wọ́n ba wa lori ọkàn arákùnrin kan ti o yapa Ọlọhun jù lọ ninu yin, iyẹn ko din nǹkan kan kù ninu ọla Mi. Ẹyin ẹrusin Mi, ti ẹni akọkọ yin ati ẹni ti o kẹhin ninu yin, eniyan yin ati awọn alujannu yin, tí wọ́n ba dúró lórí ilẹ̀ kan, ki wọn wa maa tọrọ lọ́wọ́ Mi, ki n wa maa fun èèyàn kọ̀ọ̀kan ni ohun ti n beere, ìyẹn ko din nǹkan kan ku ninu ohun ti n bẹ lọdọ Mi, àyàfi gẹgẹ bii ohun ti abẹrẹ maa dinku ti wọn ba ki i bọ inu omi òkun, ẹyin ẹrusin Mi, Mo n ṣe akọsilẹ iṣẹ yin fun yin, lẹyin naa Mo maa san ẹsan rẹ fun yin, ẹnikẹni ti o ba ri oore, ki o dúpẹ́ fun Ọlọhun, ẹni ti o ba si ri yatọ si iyẹn, ki o ma ṣe bu ẹnikan ayafi ara rẹ”.

O ni alaafia - Muslim gba a wa

Àlàyé

Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, ṣe alaye pe Ọlọhun Ọba sọ wipe Oun ti ṣe àbòsí ni eewọ fun ara Oun, O si ṣe àbòsí ni eewọ láàrin àwọn ẹ̀dá Rẹ̀; nitori naa ki ẹni kankan má ṣe abosi fun ẹlòmíràn, Ati pe gbogbo ẹda ni o ṣina kúrò ni oju ọna otitọ afi pẹlu itọsọna ati kòńgẹ́ Ọlọhun, ẹnikẹni ti o ba beere rẹ lọwọ Ọlọhun, Ọlọhun yoo fun un ni kongẹ ati itọsọna, Ati pe awọn ẹda n bukaata si Ọlọhun, wọn si nilo Rẹ ni gbogbo awọn bukaata wọn, ẹnikẹni ti o ba beere lọwọ Ọlọhun, yoo gbọ́ bukaata rẹ, yoo si tó o, Wọ́n sì ń dẹ́ṣẹ̀ lóru àti ní ọ̀sán, Ọlọhun Ọ̀gá Ògo a sì máa bo àṣírí, a si maa ṣe amojukuro nígbà tí ẹrú bá tọrọ àforíjìn, Wọn ko si ni ikapa lati fi ara ni Ọlọhun tabi ṣe E ni anfaani kankan, Ti wọn ba si wa lori ọkàn arákùnrin kan ti o paya Ọlọhun ju lọ, ipaya wọn ko ṣe alekun ọlá Ọlọhun, Ti wọn ba si wa lori ọkàn arákùnrin kan ti o yapa Ọlọhun jù, iyapa wọn ko din nǹkan kan kù ninu ọla Ọlọhun; torí pé ọ̀lẹ ni wọn ti wọn si n bukaata si Ọlọhun ni gbogbo iṣesi ati asiko ati aaye, Oun si ni Ọlọ́rọ̀, mimọ ni fun Un, Ti wọn ba duro ni ààyè kan, èèyàn wọn ati alujannu wọn, akọkọ wọn ati ìkẹyìn wọn, ti wọn wa n tọrọ nǹkan lọ́dọ̀ Ọlọhun, ki O wa maa fun ẹni kọọkan wọn ni ohun ti n beere, ìyẹn ko din nǹkan kan ku ninu ohun ti n bẹ ni ọdọ Ọlọhun, o da bii abẹrẹ ti wọn ba ki i bọ inu òkun, lẹyin naa ki wọn wa mu u jáde, nǹkan kan ko dínkù ninu òkun pẹ̀lú ìyẹn, eléyìí ri bẹ́ẹ̀ tori pípé ọrọ̀ Rẹ, ògo ni fun Un.
Ati pe Ọlọhun, mimọ ni fun Un, pa iṣẹ́ awọn ẹru Rẹ mọ, O si ṣe àkọsílẹ̀ wọn, lẹyin naa yoo san wọn ni ẹsan lori rẹ ni Ọjọ Ajinde, ẹni tí ó bá ri ẹsan iṣẹ rẹ ni oore, ki o dúpẹ́ fun Ọlọhun lori pe O fi ṣe kongẹ lati tẹle àṣẹ Rẹ, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì rí ẹ̀san iṣẹ́ rẹ̀ ní ohun mìíràn yàtọ̀ sí èyí, kò gbọ́dọ̀ dá ẹnì kan lẹ́bi bí kò ṣe ẹ̀mí rẹ̀ ti maa n pàṣẹ aburu, èyí tí ó mú kí ó pàdánù.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Hadiisi yii wa nínú ohun ti Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a, gba wa lati ọdọ Oluwa rẹ, ati pe a n pe e ni Hadith Qudsiy tabi Hadith Ilaahiy, oun ni eyi ti gbólóhùn rẹ ati itumọ rẹ wa lati ọdọ Ọlọhun. Sibẹsibẹ, ko ni awọn ìròyìn Al-Qur’an ti o ṣe iyatọ rẹ si ohunkohun miiran, gẹgẹ bii ìjọsìn pẹ̀lú kika rẹ, ati ṣíṣe imọra ti a ba fẹ kà á, ati ipenija, ati àìní ikapa lati mu irú rẹ wa, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
  2. Ohun ti ó bá ṣẹlẹ̀ sí àwọn ẹrú bíi ìmọ̀ tàbí ìtọ́sọ́nà, pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà àti ẹ̀kọ́ Ọlọ́hun ni.
  3. Ohunkohun ti o ba ṣẹlẹ̀ si ẹrú ni oore, ninu ọlá Ọlọhun t’O ga ni, ohunkohun ti o ba si ṣẹlẹ̀ si i ni aburú, lati ọdọ ara rẹ ati ifẹ-inu rẹ ni.
  4. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe dáadáa jẹ́ nípa kongẹ Ọlọ́hun, ẹ̀san rẹ̀ sì jẹ́ ọlá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ọpẹ ni fún Un, ẹni tí ó bá sì ṣe aburú, kò gbọdọ bu ẹnì kankan bí kò ṣe ara rẹ̀.
Àlékún