عن ابن عباس رضي الله عنهما قال:
كُنْتُ خَلْفَ رَسُولِ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ يَوْمًا، فَقَالَ: «يَا غُلَامُ، إِنِّي أُعَلِّمُكَ كَلِمَاتٍ، احْفَظِ اللهَ يَحْفَظْكَ، احْفَظِ اللهَ تَجِدْهُ تُجَاهَكَ، إِذَا سَأَلْتَ فَاسْأَلِ اللهَ، وَإِذَا اسْتَعَنْتَ فَاسْتَعِنْ بِاللهِ، وَاعْلَمْ أَنَّ الْأُمَّةَ لَوِ اجْتَمَعَتْ عَلَى أَنْ يَنْفَعُوكَ بِشَيْءٍ، لَمْ يَنْفَعُوكَ إِلَّا بِشَيْءٍ قَدْ كَتَبَهُ اللهُ لَكَ، وَلَوِ اجْتَمَعُوا عَلَى أَنْ يَضُرُّوكَ بِشَيْءٍ، لَمْ يَضُرُّوكَ إِلَّا بِشَيْءٍ قَدْ كَتَبَهُ اللهُ عَلَيْكَ، رُفِعَتِ الْأَقْلَامُ وَجَفَّتِ الصُّحُفُ».
[صحيح] - [رواه الترمذي] - [سنن الترمذي: 2516]
المزيــد ...
Lati ọdọ Ibnu Abbas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe:
“Mo wa lẹyin Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni ọjọ kan, o wa sọ pe: “Irẹ ọmọkunrin yii, emi yoo kọ ọ ni àwọn ọrọ kan pe: Máa ṣọ́ Ọlọhun, yoo si daabo bo ọ. Maa ṣọ Ọlọhun, iwọ yoo ri I ni iwaju rẹ. Ti o ba beere, beere lọwọ Ọlọhun, ati pe nígbà tí o ba wa iranlọwọ, wa iranlọwọ Ọlọhun. Mọ pe ti gbogbo ẹda ba pejọ lati ṣe nkan lati ṣe anfaani fun ọ, wọn ko nii ṣe àǹfààní kankan fun ọ rara ayafi pẹ̀lú nǹkan ti Ọlọhun ti kọ fun ọ. Ati pe ti wọn ba pejọ lati ṣe nkan lati ṣe ipalara fun ọ, wọn ko nii ṣe ipalara fun ọ rara ayafi pẹ̀lú nǹkan ti Allah ti kọ fun ọ. Wọn ti gbé àwọn ìkọ̀wé sókè, àwọn tákàdá si ti gbẹ.”
[O ni alaafia] - [Tirmiziy ni o gba a wa] - [Sunanu ti Tirmidhiy - 2516]
Ibnu Abbaas- ki Ọlọhun yọnu si i- n sọ pé oun kéré nígbà tí oun n gun nǹkan ọ̀gùn pẹ̀lú Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o wa sọ pé: Mo maa kọ ẹ ni àwọn nǹkan kan ti Ọlọhun maa jẹ ki wọn ṣe ọ ni anfaani:
Ṣọ́ Ọlọhun pẹlu ṣiṣọ àwọn àṣẹ Rẹ̀ ati jíjìnnà si awọn nǹkan tí O kọ̀, ki O maa ri ọ nibi itẹle àṣẹ Rẹ ati awọn iṣẹ ti a fi n sunmọ Ọlọhun, ki O si má ri ọ nibi awọn ìyapa ati ẹṣẹ, tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀san rẹ ni kí Ọlọ́run dáàbò bò ọ lọ́wọ́ nǹkan ìkórìíra ayé àti ọjọ́ ìkẹyìn, yoo sì ràn ọ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ rẹ níbikíbi tí o bá lọ.
Ti o ba fẹ tọrọ nnkan, Ọlọhun nikan ni ki o bi; tori pe Oun nikan ni O maa n da onibeere lóhùn.
Ti o ba fẹ iranlọwọ, Ọlọhun nìkan ni ki o wa iranlọwọ Rẹ̀.
Ki o ni amọdaju pe anfaani kankan ko lee ṣẹlẹ̀ si ẹ kódà ki gbogbo àwọn ará ilẹ̀ kójọ lati ṣe ọ ni anfaani ayafi ohun ti Ọlọhun ba kọ fun ẹ, inira kankan ko si lee ṣẹlẹ̀ si ẹ kódà ki gbogbo àwọn ara ilẹ̀ kójọ láti fi ìnira kan ọ àyàfi ohun tí Ọlọhun ba ti kádàrá fun ẹ.
Ati pe Ọlọhun ti kọ àlámọ̀rí yii, O si kádàrá rẹ ni ibamu si ọgbọ́n àti imọ Rẹ, ko si àyípadà fun nǹkan ti Ọlọhun kọ.