+ -

عَنْ ‌أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه قَالَ:
قَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ لِعَمِّهِ: «قُلْ: لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ، أَشْهَدُ لَكَ بِهَا يَوْمَ الْقِيَامَةِ»، قَالَ: لَوْلَا أَنْ تُعَيِّرَنِي قُرَيْشٌ، يَقُولُونَ: إِنَّمَا حَمَلَهُ عَلَى ذَلِكَ الْجَزَعُ لَأَقْرَرْتُ بِهَا عَيْنَكَ. فَأَنْزَلَ اللهُ: {إِنَّكَ لا تَهْدِي مَنْ أَحْبَبْتَ وَلَكِنَّ اللهَ يَهْدِي مَنْ يَشَاءُ } [القصص: 56].

[صحيح] - [رواه مسلم]
المزيــد ...

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe:
Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun àbúrò bàbá rẹ̀ pé: "c2">“Sọ pe: LAA ILAAHA ILLALLOOH, maa fi jẹ́rìí fun ọ ni Ọjọ́ Àjíǹde”, o sọ pe: Ti kii ba ṣe pe àwọn Quraysh maa bu mi ni, ti wọn maa sọ pé: Ìbẹ̀rù ni o mu un sọ ọ́, mi o ba fi dùn ọ́ nínú. Ni Ọlọhun wa sọ aaya yii kalẹ̀: {Dájúdájú ìwọ kò lè fi ọ̀nà mọ ẹni tí o fẹ́ràn, ṣùgbọ́n Allāhu l’Ó ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí Ó bá fẹ́} [Al-Qasas: 56].

O ni alaafia - Muslim gba a wa

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa lati ọdọ aburo baba rẹ tii ṣe Abu Toolib ti o si n pọ́kàkà ikú lọ́wọ́- pe ki o pe LAA ILAAHA ILLALLOOH, ki o fi le ṣìpẹ̀ fun un ni Ọjọ́ Àjíǹde, tí o si maa jẹrii fun un pe o gba Isilaamu, ó kọ̀ lati wí gbólóhùn ijẹrii naa ni ìpayà pe ki awọn Quraysh ma bu oun, ti wọn a maa sọ nipa oun pé: O gba Isilaamu tori ibẹru ikú ati ọ̀lẹ! O wa sọ fun Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe: Ti kii ba ṣe iyẹn ni, mi o ba dùn ọ́ nínú pẹ̀lú ki n wí gbólóhùn ijẹrii naa, mi o ba ṣe nǹkan ti o n fẹ́ titi ti wàá fi yọnu! Ni Ọlọhun ti ọla Rẹ ga wa sọ aaya kalẹ̀ ti n tọka si pe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ko ni ikapa ìtọ́sọ́nà ti kòńgẹ́ sinu Isilaamu, ṣùgbọ́n Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn nìkan ni O maa n fi ẹni tí Ó ba fẹ ṣe kongẹ. Ati pe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n fi ẹ̀dá mọ̀nà pẹlu itọka ati àlàyé ati ìtọ́sọ́nà ati ipepe lọ si ojú ọ̀nà tààrà.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Tọ́kì Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Vietnamese Èdè Hausa Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Burmese Thai Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. A kii fi òdodo silẹ ni ibẹru ohun ti àwọn èèyàn maa sọ.
  2. Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni ikapa ìtọ́sọ́nà ti itọka ati ìjúwe, ṣùgbọ́n ko ni ikapa ìtọ́sọ́nà ti kòńgẹ́.
  3. Abẹwo Kèfèrí ti o n ṣe aisan lati pe e sinu Isilaamu jẹ nǹkan ti o ba ofin sharia mu.
  4. Ojúkòkòrò Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori ipepe lọ si ọdọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ni gbogbo iṣesi.