عَنِ ابْنِ مَسْعُودٍ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُ، قَالَ:
قَالَ رَجُلٌ: يَا رَسُولَ اللهِ، أَنُؤَاخَذُ بِمَا عَمِلْنَا فِي الْجَاهِلِيَّةِ؟ قَالَ: «مَنْ أَحْسَنَ فِي الْإِسْلَامِ لَمْ يُؤَاخَذْ بِمَا عَمِلَ فِي الْجَاهِلِيَّةِ، وَمَنْ أَسَاءَ فِي الْإِسْلَامِ أُخِذَ بِالْأَوَّلِ وَالْآخِرِ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 6921]
المزيــد ...
Lati ọdọ Ibnu Mas’ud- ki Ọlọhun yọnu si i-, o sọ pe:
Arakunrin kan sọ pe: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, njẹ wọn maa ba wa wí nípa nnkan ti a ṣe ni asiko aimọkan? O sọ pe: “Ẹni ti o ba ṣe daadaa ninu Isilaamu wọn ko nii ba a wí nípa nnkan ti o ṣe ni asiko aimọkan, ati pe ẹni ti o ba ṣe aburu ninu Isilaamu wọn maa ba a wí nípa akọkọ ati igbẹyin”.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 6921]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé ọla ti o n bẹ fun wiwọ inu Isilaamu, Ati pe dajudaju ẹni ti o ba gba Isilaamu ti Isilaamu rẹ si daa ti o si jẹ olumọkanga olododo; wọn ko nii ṣe ìṣirò ìṣẹ́ nnkan ti o ba ṣe ni asiko aimọkan ninu awọn ẹṣẹ, Ati pe ẹni ti o ba ṣe aburu ninu Isilaamu pẹ̀lú ki o jẹ ṣọbẹ-ṣelu tabi ki o ṣẹri pada kuro nibi ẹsin rẹ; wọn maa ṣe ìṣirò ìṣẹ́ nnkan ti o ṣe ninu aigbagbọ ati nnkan ti o ṣe ninu Isilaamu.