عن أبي هريرة رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«الْإِيمَانُ بِضْعٌ وَسَبْعُونَ -أَوْ بِضْعٌ وَسِتُّونَ- شُعْبَةً، فَأَفْضَلُهَا قَوْلُ لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ، وَأَدْنَاهَا إِمَاطَةُ الْأَذَى عَنِ الطَّرِيقِ، وَالْحَيَاءُ شُعْبَةٌ مِنَ الْإِيمَانِ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح مسلم: 35]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, sọ pe:
“Igbagbọ jẹ ipin aadọrin ati nnkankan- tabi ọgọta ati nnkankan-, eyi ti o ni ọla julọ nibẹ ni gbolohun Laa ilaaha illallohu, eyi ti o kere julọ nibẹ ni mimu suta kuro lọna, ati pe itiju jẹ ipin kan ninu igbagbọ”.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Muslim - 35]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju igbagbọ jẹ awọn ipin kan ati awọn iwa ti wọn pọ, o ko awọn iṣẹ ati awọn adisọkan ati awọn ọrọ kan sinu.
Ati pe eyi to ga julọ ninu iwa igbagbọ ti o si daa julọ nibẹ ni gbolohun: “Laa ilaaha illallohu”, ni mimọ ìtumọ̀ rẹ, ni ṣíṣe iṣẹ pẹlu nnkan ti o da le lori, bii pe dajudaju Ọlọhun ni Ọlọhun Ọba Ọkan ṣoṣo ti O lẹtọọ si ijọsin ni Oun nikan ṣoṣo yatọ si ẹni ti o yatọ si I.
Ati pe eyi ti o kere julọ ninu awọn iṣẹ igbagbọ ni mimu gbogbo nnkan ti o le ko suta ba awọn eniyan kuro ni awọn oju ọna wọn.
Lẹyin naa Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju itiju wa ninu iwa igbagbọ, oun ni awọn iwa kan ti o maa n muni ṣe nǹkan daadaa, ti o si maa n muni gbé iwa buruku ju silẹ.