+ -

عن أبي بَشير الأنصاري رضي الله عنه:
أَنَّهُ كَانَ مَعَ رَسُولِ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ فِي بَعْضِ أَسْفَارِهِ، قَالَ: فَأَرْسَلَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ رَسُولًا -وَالنَّاسُ فِي مَبِيتِهِمْ-: «لَا يَبْقَيَنَّ فِي رَقَبَةِ بَعِيرٍ قِلَادَةٌ مِنْ وَتَرٍ أَوْ قِلَادَةٌ إِلَّا قُطِعَتْ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح مسلم: 2115]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Bashir Al-Ansari- ki Ọlọhun yọnu si i-:
O wa pẹlu ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni apakan awọn irin ajo rẹ, o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ran ojiṣẹ kan niṣẹ- ti awọn eniyan si wa ninu ibusun wọn pe-: “Ẹ̀gbà ọrùn kan ti wọn fi okùn ọfà tín-ín-rín ṣe ko gbọdọ ṣẹku ni ọrun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tabi ẹgba ọrun kan afi ki wọn ge e”.

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Muslim - 2115]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ni apakan awọn ìrìn-àjò rẹ, ti awọn eniyan wa ni aaye orun wọn ti wọn maa n sun ni ìrìn-àjò wọn ati tẹnti wọn, bayii ni o wa ran ẹnikan si awọn eniyan ki o pa wọn láṣẹ láti gé awọn ẹgba ọrun ti wọn gbé kọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ lọrun, boya o jẹ eyi ti wọn ṣe latara okun tín-ín-rín ni- tàbí ti wọn ṣe latara nǹkan mìíràn gẹgẹ bii agogo tabi irin ẹsẹ ẹranko, ìyẹn ri bẹẹ; nitori pe wọn maa n gbe e kọ́ ọ lọrun lati fi ṣọ́ra kuro nibi ojúkójú, wọn wa pa wọn láṣẹ lati ge e; nitori ko lee dá aburu padà kuro fun wọn, ati pe anfaani ati inira, ọwọ Ọlọhun nìkan ṣoṣo ni o wa ti ko si orogun fun Un.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè Kannada الولوف البلغارية Ti ede Azerbaijan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣíṣe siso awọn okun ọfà tín-ín-rín ati awọn ẹgba ọrun mọ ọrun ni eewọ lati fi fa anfaani wa tabi lati ti aburu dànù; nitori pe ìyẹn wa ninu ẹbọ.
  2. Siso ẹgba ọrun ti wọn fi nǹkan to yatọ si okun ọfà tín-ín-rín ṣe mọ́ ọrùn ti o ba jẹ ti ọ̀ṣọ́, tabi lati fi da ẹranko, tabi lati fi so ó mọ́lẹ̀, ko si ohun ti o burú nibẹ.
  3. Jijẹ dandan titako aburu bi ikapa ba ṣe mọ.
  4. Jijẹ dandan siso ọkan papọ mọ Ọlọhun nikan ṣoṣo ti ko si orogun fun Un.