عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه أَنَّهُ قَالَ:
قِيلَ: يَا رَسُولَ اللهِ، مَنْ أَسْعَدُ النَّاسِ بِشَفَاعَتِكَ يَوْمَ الْقِيَامَةِ؟ قَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: «لَقَدْ ظَنَنْتُ يَا أَبَا هُرَيْرَةَ أَنْ لَا يَسْأَلَنِي عَنْ هَذَا الْحَدِيثِ أَحَدٌ أَوَّلُ مِنْكَ؛ لِمَا رَأَيْتُ مِنْ حِرْصِكَ عَلَى الْحَدِيثِ، أَسْعَدُ النَّاسِ بِشَفَاعَتِي يَوْمَ الْقِيَامَةِ، مَنْ قَالَ لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ خَالِصًا مِنْ قَلْبِهِ أَوْ نَفْسِهِ»».
[صحيح] - [رواه البخاري] - [صحيح البخاري: 99]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Hurairah - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju ó sọ pé:
Wọ́n sọ pé: Iwọ Ojiṣẹ Ọlọhun, ta ni yoo ṣoriire jù ninu awọn eniyan pẹlu ìṣìpẹ̀ rẹ ni ọjọ Igbende? Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - dahun bayii wi pe: "Irẹ Abu Hurairah, mo ti rò naa pé ko si ẹnikan ti yoo bi mi leere nipa hadiisi yii saaju rẹ, nigba ti mo ti ri itaraṣaṣa rẹ si imọ hadiisi, Ẹnití ó maa ṣoriire jù pẹlu ìṣìpẹ̀ mi ní ọjọ Igbende, oun ni ẹniti ó bá sọ pé ko si ọlọhun miran ayafi Ọlọhun Allah, tí ó ṣo bẹẹ pẹlu ododo lati inu ọkàn rẹ̀".
[O ni alaafia] - [Bukhaariy gba a wa] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 99]
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n fun wa ni iro pé dajudaju ẹniti ó maa ṣoriire jù pẹlu ìṣìpẹ̀ oun ni ọjọ Igbende ni ẹnikẹni tí ó bá sọ pé: "Ko si ọlọhun miran ayafi Ọlọhun Allah pẹlu ododo lati inu ọkan rẹ̀" iyẹn ni pe: ko si ẹnikẹni ti a gbọdọ jọsin fun pẹlu ododo ayafi Ọlọhun Allah, ati pe ó gbọdọ là kuro nibi ẹbọ ati kárími.