عن سَعِيدِ بْنِ الْمُسَيَّبِ، عَنْ أَبِيهِ قَالَ:
لَمَّا حَضَرَتْ أَبَا طَالِبٍ الْوَفَاةُ، جَاءَهُ رَسُولُ اللهِ صلى الله عليه وسلم فَوَجَدَ عِنْدَهُ أَبَا جَهْلٍ وَعَبْدَ اللهِ بْنَ أَبِي أُمَيَّةَ بْنِ الْمُغِيرَةِ، فَقَالَ: «أَيْ عَمِّ، قُلْ: لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ، كَلِمَةً أُحَاجُّ لَكَ بِهَا عِنْدَ اللهِ»، فَقَالَ أَبُو جَهْلٍ وَعَبْدُ اللهِ بْنُ أَبِي أُمَيَّةَ: أَتَرْغَبُ عَنْ مِلَّةِ عَبْدِ الْمُطَّلِبِ، فَلَمْ يَزَلْ رَسُولُ اللهِ صلى الله عليه وسلم يَعْرِضُهَا عَلَيْهِ، وَيُعِيدَانِهِ بِتِلْكَ الْمَقَالَةِ، حَتَّى قَالَ أَبُو طَالِبٍ آخِرَ مَا كَلَّمَهُمْ: عَلَى مِلَّةِ عَبْدِ الْمُطَّلِبِ، وَأَبَى أَنْ يَقُولَ: لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ، قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللهِ صلى الله عليه وسلم: «وَاللهِ لَأَسْتَغْفِرَنَّ لَكَ مَا لَمْ أُنْهَ عَنْكَ»، فَأَنْزَلَ اللهُ: {مَا كَانَ لِلنَّبِيِّ وَالَّذِينَ آمَنُوا أَنْ يَسْتَغْفِرُوا لِلْمُشْرِكِينَ} [التوبة: 113]، وَأَنْزَلَ اللهُ فِي أَبِي طَالِبٍ، فَقَالَ لِرَسُولِ اللهِ صلى الله عليه وسلم: {إِنَّكَ لا تَهْدِي مَنْ أَحْبَبْتَ وَلَكِنَّ اللهَ يَهْدِي مَنْ يَشَاءُ} [القصص: 56].
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 4772]
المزيــد ...
Lati ọdọ Saheed ọmọ Al-Musayyab, láti ọ̀dọ̀ bàbá rẹ, o sọ pé:
Nigba ti asiko iku Abu Taalib to, Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa ba a, o si ba Abu Jahli ati Abdullāh ọmọ Abu Umayyah ọmọ Mughiirah ni ọdọ rẹ, ni o wa sọ pe: «Irẹ ọmọ-iya baba mi, sọ pe: Laa illaha illā Allāhu, gbolohun kan ni ti maa fi jẹrii gbe ọ ni ọdọ Allāhu», ni Abu Jahli ati Abdullāh ọmọ Abu Umayyah wa sọ pe: Ṣe o fẹ gunri kuro nibi ilana Abdul Mutalibi ni, Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o si yẹ lẹni ti n fi lọ̀ ọ́ pe ki o wi i, ti awọn mejeeji naa si n paara ọrọ naa, titi ti Abu Taalib fi sọ nkan ti o ba wọn sọ gbẹyin pe: Lori ilana Abdul Mutalibi, ti o si kọ lati sọ: Laa illaha illā Allāhu, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Mo fi Ọlọhun bura maa maa tọrọ aforijin fun ọ ti wọn o ba ti kọ fun mi kuro nibẹ», ni Ọlọhun wa sọ ọ kalẹ pe: {Kò yẹ fún Ànábì àti àwọn t’ó gbàgbọ́ lódodo láti tọrọ àforíjìn fún àwọn ọ̀sẹbọ} [Al Taobah: 113]. Ni Ọlọhun tun wa sọ ọ kalẹ nipa Abu Taalib, ti O si sọ fun Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - pe ﴾Dájúdájú ìwọ kò lè fi ọ̀nà mọ ẹni tí o fẹ́ràn, ṣùgbọ́n Allāhu l’Ó ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí Ó bá fẹ́﴿ [Al Qasas: 56].
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 4772]
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wọle tọ ọmọ-iya baba rẹ Abu Taalib ti o n pọka iku lọwọ, ni o wa sọ fun un pe: Irẹ ọmọ-iya baba mi, sọ pe "laa ilaaha illa Allāhu", gbolohun kan ti maa fi jẹrii gbe ọ ni ọdọ Allāhu, Ni Abu Jahli ati Abdullāh ọmọ Abu Umayyah wa sọ pe: Irẹ Abu Taalib, ṣe waa fi ilana baba rẹ Abdul Mutalibi silẹ ni? Oun si ni jijọsin fun awọn oriṣa, awọn mejeeji o si yẹ lẹni ti n ba a sọrọ titi ti o fi sọ ọrọ igbẹyin ti o ba wọn sọ pe: Lori ilana Abdul Mutalibi, ilana ẹbọ, ati jijọsin fun awọn oriṣa. Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ pe: Maa ṣe adua aforijin fun ọ lopin igba ti Oluwa mi o ba ti kọ fun mi kuro nibẹ, ni gbolohun Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ba sọkalẹ pe: {Kò yẹ fún Ànábì àti àwọn t’ó gbàgbọ́ lódodo láti tọrọ àforíjìn fún àwọn ọ̀sẹbọ, wọn ìbáà jẹ́ ẹbí, lẹ́yìn tí ó ti hàn sí wọn pé dájúdájú èrò inú iná Jẹhīm ni wọ́n} [Al Taobah: 113], Ni o wa sọkalẹ nipa Abu Taalib gbolohun Ọlọhun ti ọla Rẹ ga pe: ﴾Dájúdájú ìwọ kò lè fi ọ̀nà mọ ẹni tí o fẹ́ràn, ṣùgbọ́n Allāhu l’Ó ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí Ó bá fẹ́. Àti pé Ó nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùmọ̀nà﴿ [Al Qaṣaṣ: 56], Dajudaju oo le fun ẹni ti o ba wu ẹ ni imọna, ati pe nkan ti o jẹ dandan fun ọ ni ki o jiṣẹ, ati pe Ọlọhun ni o máa n fi ẹni ti o ba wu U mọ ọna.