+ -

عَنْ سَهْلُ بْنُ سَعْدٍ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُ أَنَّ رَسُولَ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ يَوْمَ خَيْبَرَ:
«لَأُعْطِيَنَّ هَذِهِ الرَّايَةَ غَدًا رَجُلًا يَفْتَحُ اللَّهُ عَلَى يَدَيْهِ، يُحِبُّ اللَّهَ وَرَسُولَهُ وَيُحِبُّهُ اللَّهُ وَرَسُولُهُ»، قَالَ: فَبَاتَ النَّاسُ يَدُوكُونَ لَيْلَتَهُمْ أَيُّهُمْ يُعْطَاهَا، فَلَمَّا أَصْبَحَ النَّاسُ غَدَوْا عَلَى رَسُولِ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ كُلُّهُمْ يَرْجُو أَنْ يُعْطَاهَا، فَقَالَ: «أَيْنَ عَلِيُّ بْنُ أَبِي طَالِبٍ؟» فَقِيلَ: هُوَ يَا رَسُولَ اللَّهِ يَشْتَكِي عَيْنَيْهِ، قَالَ: «فَأَرْسِلُوا إِلَيْهِ»، فَأُتِيَ بِهِ فَبَصَقَ رَسُولُ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ فِي عَيْنَيْهِ وَدَعَا لَهُ، فَبَرَأَ حَتَّى كَأَنْ لَمْ يَكُنْ بِهِ وَجَعٌ، فَأَعْطَاهُ الرَّايَةَ، فَقَالَ عَلِيٌّ: يَا رَسُولَ اللَّهِ، أُقَاتِلُهُمْ حَتَّى يَكُونُوا مِثْلَنَا؟ فَقَالَ: «انْفُذْ عَلَى رِسْلِكَ حَتَّى تَنْزِلَ بِسَاحَتِهِمْ، ثُمَّ ادْعُهُمْ إِلَى الإِسْلاَمِ، وَأَخْبِرْهُمْ بِمَا يَجِبُ عَلَيْهِمْ مِنْ حَقِّ اللَّهِ فِيهِ، فَوَاللَّهِ لَأَنْ يَهْدِيَ اللَّهُ بِكَ رَجُلًا وَاحِدًا، خَيْرٌ لَكَ مِنْ أَنْ يَكُونَ لَكَ حُمْرُ النَّعَمِ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 4210]
المزيــد ...

Lati ọdọ Sahl ọmọ Sa'd- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ ni ọjọ́ Khaibar pé:
Dajudaju maa fun arakunrin kan ni asia yii ni ọla ti Ọlọhun maa ti ipasẹ rẹ fun wa ni iṣẹgun, o nífẹ̀ẹ́ Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ, Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ naa nífẹ̀ẹ́ rẹ”, o sọ pe: Àwọn ènìyàn sùn ní alẹ́ náà tí wọ́n ń jiroro laarin ara wọn tani wọn yoo fun.” Nígbà ti ilẹ̀ mọ́, àwọn èèyàn lọ ba ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti ọkọọkan ninu wọn si n fẹ ki wọn fun oun, o sọ pe: “Ibo ni ‘Ali ọmọ Abu Talib wà”? Wọn sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ojú n dùn ún. O sọ pe: “Ẹ ranṣẹ si i”, wọn si mu u wa ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa tutọ́ si oju rẹ mejeeji, o si ṣe adura fun un, o si gbadun gẹgẹ bii pe inira kan kan ko mu u, o wa fun un ni asia náà. Ali wa sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ki n maa ba wọn ja titi wọn fi maa da bii wa? O sọ pe: “Maa lọ ni pẹlẹpẹlẹ titi waa fi dé agbegbe wọn, lẹyin naa pe wọn sinu Isilaamu, sọ nnkan ti o jẹ dandan le wọn lori ninu ẹtọ Ọlọhun fun wọn nibẹ. Mo fi Ọlọhun bura, ki Ọlọhun fi arákùnrin kan ṣoṣo mọna latara rẹ, o loore fun ẹ ju ki o ni ràkúnmí pupa lọ".

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 4210]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun awọn saabe nípa ìṣẹ́gun awọn mùsùlùmí lori awọn Juu Khaibar ni ọjọ keji, ìyẹn maa waye lati ọwọ arakunrin kan ti oun maa fun un ni asia, oun naa ni àsíá tí àwọn ọmọ ogun maa n fi ṣe àmì wọn, Ati pe arakunrin yii ninu awọn iroyin rẹ ni pe o nífẹ̀ẹ́ Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ, ti Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ naa si nífẹ̀ẹ́ rẹ, Àwọn saabe si sùn ni alẹ ti wọn n jíròrò ti wọn si n sọ̀rọ̀ nipa pe tani wọn maa fun ni asia naa? Ni ti ìfẹ́ si iyì ńlá yii, Nigba ti o di àárọ̀ wọn lọ sọ́dọ̀ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, gbogbo wọn ni wọ́n n nírètí pé àwọn á gba iyì yìí,
Ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa beere nipa 'Ali ọmọ Abu Talib- ki Ọlọhun yọnu si i-?
Wọn sọ pé: O rẹ ẹ, ojú rẹ mejeeji n dun un.
Ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba ranṣẹ si i, wọn si de pẹlu rẹ, o wa tu itọ si oju 'Ali mejeeji ninu itọ rẹ abiyi, o ṣe adura fun un, o si gbádùn nibi aisan rẹ, o wa da gẹgẹ bii pe inira kan ko mu u tẹ́lẹ̀, o wa fun un ni asia naa, o pa a láṣẹ pẹlu pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ titi o fi maa sunmọ aaye ààbò awọn ọta ti o si maa fi gbigba Isilaamu lọ wọn, ti wọn ba da a lohun; o maa sọ fun wọn nnkan ti o jẹ dandan fun wọn ninu awọn ọran-anyan.
Lẹyin naa, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé fun 'Ali nipa ọla ti o n bẹ fun ipepe lọ si oju ọna Ọlọhun ati pe ti ipepe ba jẹ okunfa ìtọ́sọ́nà arakunrin kan ṣoṣo ìyẹn loore fun un ju ki rakunmi pupa jẹ tirẹ̀ lọ, eyi ti o ṣe pe oun ni o níye lórí julọ ninu awọn dukia larubawa, yio ni i tabi ki o fi ta ọrẹ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania الموري Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الجورجية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ọla ti o n bẹ fun 'Ali ọmọ Abu Talib- ki Ọlọhun yọnu si i-, ati ijẹrii ojiṣẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- fun un, pẹlu ifẹ Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ fun un, ati ifẹ rẹ fun Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ.
  2. Iṣojukokoro awọn saabe lori daadaa ati iyara wọn lọ síbẹ̀.
  3. Ṣíṣe ẹkọ nibi ija lofin ati gbigbe aironujinlẹ ju silẹ ati awọn ohun tii ko inira ba eniyan ti ko si bukaata fun un.
  4. Ninu awọn itọka ijẹ anabi rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni ifunni ni iro rẹ nipa ibori awọn Juu, ati wiwo oju mejeeji 'Ali ọmọ Abu Talib san lati ọwọ rẹ mejeeji pẹlu iyọnda Ọlọhun.
  5. Nnkan ti a gba lero ti o tobi julọ ninu ijagun soju ọna Ọlọhun ni ki awọn eniyan wọnú Isilaamu.
  6. Dajudaju ipepe maa n ṣẹlẹ̀ díẹ̀ díẹ̀ ni, wọn kọ́kọ́ maa ni ki alaigbagbọ o wọnu Isilaamu pẹlu sisọ gbolohun ijẹrii mejeeji, lẹyin naa wọn maa pa a láṣẹ pẹlu awọn ọran-anyan Isilaamu lẹyin ìyẹn.
  7. Ọla ti o n bẹ fun ipepe lọ sinu Isilaamu, ati nnkan ti o wa nibẹ ninu oore fun ẹni ti wọn n pe ati olupepe, ẹni ti wọn n pe le mọna ti wọn si maa san olupepe lẹ́san ti o tobi.