+ -

عن عائشة رضي الله عنها عن النبي صلى الله عليه وسلم قال:
«إِنَّ أَبْغَضَ الرِّجَالِ إِلَى اللهِ الْأَلَدُّ الْخَصِمُ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 2457]
المزيــد ...

Láti ọ̀dọ̀ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pé:
“Dájúdájú èèyàn ti Ọlọhun koriira jù ni alátakò ti o le julọ”.

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 2457]

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé Ọlọhun ti ọla Rẹ ga n koriira ninu awọn èèyàn ẹni ti o le ni àtakò ti o si maa n sáábà ṣe àtakò, ẹni tí kii tẹrí ba fun òdodo, ti o maa n gbìyànjú láti da a pada pẹlu iyàn jíjà rẹ, tabi ki o maa ṣe àtakò lori ododo, ṣùgbọ́n o maa ki aṣeju bọ̀ ọ́, o tun maa ṣe àtakò láìní imọ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ki ẹni tí a ṣe àbòsí si beere ẹtọ rẹ nípasẹ̀ gbigbe ẹjọ́ lọ ba adajọ ti o ba òfin mu, eleyii kò kó sinu àtakò ti ko dára.
  2. Ìjiyàn ati àtakò wa ninu awọn ìpalára ahọn ti o maa n ṣe okùnfà ìpín yẹ́lẹyẹ̀lẹ ati ìkọ̀yìn-sí-ara-ẹni láàrin àwọn Musulumi.
  3. Àtakò ti o dara ni eyi ti o ba jẹ nibi òdodo, ti ọ̀nà ti a gbe e gba naa si dára, o si maa jẹ eyi ti ko dára ti o ba wa fun dida òdodo padà, ati fifi irọ́ rinlẹ, tabi ki o ma si ẹ̀rí kankan fun un.