+ -

عن جرير بن عبد الله رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«مَنْ لَا يَرْحَمِ النَّاسَ لَا يَرْحَمْهُ اللهُ عَزَّ وَجَلَّ».

[صحيح] - [متفق عليه]
المزيــد ...

Láti ọ̀dọ̀ Jariir ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
"c2">“Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn ko nii ṣàánú ẹni tí kii ba ṣàánú àwọn èèyàn”.

O ni alaafia - Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe ẹni ti kii ba ṣàánú àwọn èèyàn, Ọlọhun ko nii ṣàánú rẹ, aanu ẹrú fún ẹ̀dá Ọlọhun jẹ ọkan ninu awọn okùnfà ti o tobi ju lati ri aanu Ọlọhun ti ọla Rẹ ga gbà.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Àánú, nǹkan ti a n fẹ ni fun awọn ẹ̀dá yòókù, ṣùgbọ́n wọn dìídì dárúkọ àwọn èèyàn ni ti akolekan pẹ̀lú wọn.
  2. Aláàánú ni Ọlọhun, O maa n ṣàánú àwọn ẹrú Rẹ ti wọn ni aanu, ẹ̀san maa n wa latara iran iṣẹ ni.
  3. Aanu àwọn èèyàn kó mímú oore de ọdọ wọn sínú, ati titi aburu kuro fun wọn, ati bíbá wọn lò pọ̀ pẹlu dáadáa.