+ -

عن أبي هريرة رضي الله عنه أن رسول الله صلى الله عليه وسلم قال:
«كان رجلٌ يُدَايِنُ الناسَ، فكان يقول لفتاه: إذا أتيتَ مُعسِرًا فتجاوز عنه، لعل اللهَ يَتجاوزُ عنا، فلقي اللهَ فتجاوز عنه».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح مسلم: 1562]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Hurairah - ki Ọlọhun yọnu si i - ó ní dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pé:
"Ọkùnrin kan wà tó máa ń yá àwọn eniyan ní owo, ó sì máa ń sọ fún ọ̀dọ́kùnrin rẹ̀ pé: Ti o bá de ọdọ alaini, ki o ṣamojukuro fun un, bóyá Ọlọ́hun yoo ṣamojukuro fún awa naa, ni ọkunrin yii bá pàdé Ọlọ́hun, Ọlọ́hun sì ṣamojukuro fun un".

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Muslim - 1562]

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ nipa ọkunrin kan tí ó máa ń yá awọn eniyan ní owo gbese, tabi kí ó ta ọjà àwìn fún wọn, ó sì jẹ́ ẹniti o máa ń sọ fún ọmọ-ọdọ rẹ̀ tí o maa n lọ gba gbèsè tí awọn ènìyàn jẹ ẹ pé: Ti o bá dé ọdọ onigbese ti kò ní owo lati san gbese tó jẹ nitori ailagbara rẹ̀ "ṣamojukuro fun un"; bóyá ki o fun un ni akoko si, kí o sì ma sin in lagidi, tabi ki o gba ohun ti o wa ni ọwọ rẹ̀ naa, koda ki owo naa mai tii pe, o ṣe eleyii nitori pé ó ń fẹ́, ó sì n rankan pé kí Ọlọhun ṣamojukuro fun oun naa, ki O sì darijin oun, Nígbà ti ọkunrin yii kú, Ọlọ́hun dárí jìn in, Ó sì ṣamojukuro fun un nibi àwọn àṣìṣe rẹ̀.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف البلغارية Ti ede Azerbaijan الأكانية Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية اللينجالا المقدونية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣiṣe daadaa nibi ajọṣepọ pẹlu àwọn eniyan, ati dídáríjìn wọ́n, àti ṣiṣamojukuro fún awọn alaini aarin wọn jẹ́ ọ̀kan ninu ​​àwọn okunfa tó ga jù lọ fún lílà ẹru Ọlọhun ní Ọjọ́ Àjíǹde.
  2. Ṣiṣe daadaa sí awọn eniyan, ṣiṣe mímọ́ nibi ijọsin fun Ọlọ́hun, àti rirankan ikẹ ati àánú Rẹ̀ jẹ́ ọkan ninu ​​àwọn okunfa rírí ìdáríjìn ẹ̀ṣẹ̀.