عَنْ عَائِشَةَ أُمِّ المؤْمِنينَ رَضِيَ اللهُ عَنْهَا:
كَانَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ يَجْتَهِدُ فِي الْعَشْرِ الْأَوَاخِرِ مَا لَا يَجْتَهِدُ فِي غَيْرِهِ.
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 1175]
المزيــد ...
Lati ọdọ Aishah iya awọn olugbagbọ ododo, ki Ọlọhun yọnu si i:
Òjíṣẹ Ọlọhun (kí ikẹ ati ọla Ọlọhun máa ba) aa maa se igbiyanju ni mẹwa igbẹyin iru igbiyanju ti kii se ninu awọn ọjọ miran.
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 1175]
Ti mẹwa igbẹyin ninu osu Ramadan ba tide Anọbi (Ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba) aa maa gbiyanju ninu rẹ pẹlu ìjọsìn ati itẹle aṣẹ Ọlọhun, aa si maa se ọpọlọpọ awọn oriṣirisi iṣẹ o loore ati awọn oníranran iṣẹ daada ati ìjọsìn fún Ọlọhun eyi ti o pọ ju bi se ma ngbiyanju ni awọn ọjọ míràn lọ, ori bẹẹ nitori titobi ati ọlá ti nbẹ fún awọn òru náà ati nítorí wiwa òru abiyi.