عن أبي هريرة رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«مَنْ يَقُمْ لَيْلَةَ الْقَدْرِ إِيمَانًا وَاحْتِسَابًا غُفِرَ لَهُ مَا تَقَدَّمَ مِنْ ذَنْبِهِ»
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 35]
المزيــد ...
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Ẹni tí ó bá dìde ni oru Laelatul Kọdri ni ti igbagbọ ati ireti ẹsan ni ọdọ Ọlọhun, wọn maa fi orí ẹṣẹ rẹ ti o ṣáájú jin in”.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 35]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ fún wa nipa ọla idide ni oru Laelatul Kọdri ti o maa n wa ni mẹ́wàá ikẹyin ninu oṣù Ramadan, ati pe ẹni ti o ba gbìyànjú ninu ẹ pẹ̀lú ìrun ati adua ati kika Kuraani ati iranti, ni ẹni tí o gba a gbọ́ ati ọla ti n bẹ fun un, ti o si n reti ẹsan Ọlọhun pẹlu iṣẹ rẹ, ti kii ṣe ti ṣekarimi tabi ṣekagbọmi, wọn maa fi orí àwọn ẹṣẹ rẹ ti o ṣáájú jin in.