عن أبي هريرة رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«مَنْ يُرِدِ اللهُ بِهِ خَيْرًا يُصِبْ مِنْهُ».

[صحيح] - [رواه البخاري] - [صحيح البخاري: 5645]
المزيــد ...

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Ẹni tí Ọlọhun ba fẹ oore fún, O maa fi àdánwò kàn án”.

[O ni alaafia] - [Bukhaariy gba a wa] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 5645]

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe ti Ọlọhun ba fẹ oore fun ọkan ninu awọn ẹru Rẹ ti wọn jẹ mumini, o maa fi àdánwò kan wọn ninu ẹmi wọn ati dúkìá wọn ati ẹbi wọn, torí ìsádi Ọlọhun ti o maa ṣẹlẹ̀ si mumini ninu ẹ pẹ̀lú adua ati pipa awọn iṣẹ buruku rẹ́ ati agbega ní ipò.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Onigbagbọ òdodo maa ri oríṣiríṣi àdánwò.
  2. Àdánwò le jẹ àmì ìfẹ́ Ọlọhun fun ẹrú Rẹ, titi ti yoo fi gbe ipò rẹ ga, ti o si maa pa àṣìṣe rẹ̀ rẹ́.
  3. Ṣiṣenilojukokoro lori suuru nigba àdánwò, ki èèyàn má sì ba ara jẹ.
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Èdè: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Àlékún (67)