عَنْ مَطَرِ بْنِ عُكَامِسٍ رضي الله عنه قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«إِذَا قَضَى اللَّهُ لِعَبْدٍ أَنْ يَمُوتَ بِأَرْضٍ جَعَلَ لَهُ إِلَيْهَا حَاجَةً».

[صحيح] - [رواه الترمذي] - [سنن الترمذي: 2146]
المزيــد ...

Láti ọ̀dọ̀ Matọr ọmọ Ukaamis- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Ti Ọlọhun ba kádàrá fun ẹrú kan pé o maa kú si ilẹ̀ kan, O maa jẹ ki o ni bukaata si i.”

[O ni alaafia] - [Tirmiziy ni o gba a wa] - [Sunanu ti Tirmidhiy - 2146]

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: Ti Ọlọhun ba kádàrá fun ẹrú kan pe ki o kú sí ilẹ̀ kan ti ko si si nibẹ; O maa jẹ ki o ni bukaata si i, yoo waa wa si ibẹ, wọn si maa gba ẹ̀mí rẹ nibẹ.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Hadiisi naa n jẹrii si òdodo ọ̀rọ̀ Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn ti O sọ pe: {Ẹ̀mí kan kò sì mọ ilẹ̀ wo l’ó máa kú sí}.
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Èdè: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Àlékún (65)