عن أبي هريرة رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«مَنْ كَذَبَ عَلَيَّ مُتَعَمِّدًا فَلْيَتَبَوَّأْ مَقْعَدَهُ مِنَ النَّارِ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 110]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
"Ẹni ti o ba mọọmọ parọ mọ mi, ki o yaa lọ wa ibùjókòó rẹ ninu ina".
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 110]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju ẹni ti o ba mọọmọ parọ mọ ọn, pẹlu fifi ọrọ kan tabi iṣẹ kan ti si ọdọ rẹ ni ti irọ, dajudaju ibujokoo kan n bẹ fun un ni ọrun ninu ina; ki o maa jẹ ẹsan fun un lori pipa irọ mọ ọn.