+ -

عن عبد الله بن عمرو رضي الله عنهما أن النبي صلى الله عليه وسلم قال:
«بَلِّغُوا عَنِّي وَلَوْ آيَةً، وَحَدِّثُوا عَنْ بَنِي إِسْرَائِيلَ وَلَا حَرَجَ، وَمَنْ كَذَبَ عَلَيَّ مُتَعَمِّدًا فَلْيَتَبَوَّأْ مَقْعَدَهُ مِنَ النَّارِ».

[صحيح] - [رواه البخاري]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abdullah ọmọ ‘Amr - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - ó ní dajudaju Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pé:
"Ẹ jẹ́ iṣẹ mi koda bo ṣe pẹlu aayah kan, kí ẹ sì sọrọ nipa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kò sí aburu nibẹ, ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ̀ọ́mọ̀ parọ́ mọ́ mi, kí onitọhun yaa tètè mú ibùjókòó rẹ̀ nínú Iná".

O ni alaafia - Bukhaariy gba a wa

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlohun maa ba a - n pàṣẹ pé ki a gbé ìmọ̀ oun kaakiri, yala o jẹ lati inu Al-Qur’an ni tabi lati inu Sunna, koda ki nkan naa jẹ kekere gẹgẹ bii aayah kan pere lati inu Al-Qur’an tabi Hadiisi kan pere, pẹlu majẹmu pé ki olujiṣẹ naa jẹ́ onimimọ nipa nkan ti ó fẹ́ jiṣẹ rẹ̀, tí ó sì fẹ́ kéde rẹ̀. Lẹyin naa ni Anabi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- ṣalaye pé ko si aburu pẹlu sisọrọ nipa awọn ọmọ Ísírẹ́lì, ati nipa awọn ìsẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn, pẹlu pé kó ṣá ti má tako ofin sharia tiwa. Lẹyin naa, ó wá wa ní isọra kuro nibi píparọ́ mọ́ òun, nitori pé ẹnikẹni tí ó bá mọ̀ọ́mọ̀ parọ mọ oun, kí ó yaa tètè gba aaye kalẹ̀ fun ara rẹ̀ ninu ina.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ìgbani níyànjú lati maa kéde òfin sharia Ọlọ́hun, àti pé ènìyàn gbọ́dọ̀ kéde ohun tí ó bá há sórí, tí ó sì gbágbọ̀yéé rẹ̀, koda bó jẹ́ pé díẹ̀ ni.
  2. Ọ̀ranyàn ni wíwá ìmọ̀ ofin sharia; kí a lè jọsin fun Ọlọhun ní ìrọ̀rùn, kí a sì lè kede sharia Rẹ̀ ní àwòrán tó lalaafia.
  3. Ọ̀ranyàn ni kí a ri i dájú pé èyíkéyìí hadiisi ní alaafia siwaju kí a tó kede rẹ̀, nitori kí a má baa kó sí inu ìlérí tó lekoko yii.
  4. Ìgbani níyanju lati maa sọ ododo ati ìmáa ṣọra nibi ọrọ sisọ, kí a má baa kó sinu irọ́, paapaa julọ ninu ofin Ọlọhun Ọba.