عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُ:
أَنَّ أَعْرَابِيًّا أَتَى النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، فَقَالَ: دُلَّنِي عَلَى عَمَلٍ إِذَا عَمِلْتُهُ دَخَلْتُ الجَنَّةَ، قَالَ: «تَعْبُدُ اللَّهَ لاَ تُشْرِكُ بِهِ شَيْئًا، وَتُقِيمُ الصَّلاَةَ المَكْتُوبَةَ، وَتُؤَدِّي الزَّكَاةَ المَفْرُوضَةَ، وَتَصُومُ رَمَضَانَ» قَالَ: وَالَّذِي نَفْسِي بِيَدِهِ لاَ أَزِيدُ عَلَى هَذَا، فَلَمَّا وَلَّى قَالَ النَّبِيُّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: «مَنْ سَرَّهُ أَنْ يَنْظُرَ إِلَى رَجُلٍ مِنْ أَهْلِ الجَنَّةِ، فَلْيَنْظُرْ إِلَى هَذَا».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 1397]
المزيــد ...
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i-:
Dajudaju larubawa oko kan wa ba Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o sọ pe: Tọ mi sọ́nà lori iṣẹ kan ti mo ba ṣe e maa wọ alujanna, o sọ pe: "Maa jọsin fun Ọlọhun ki o si ma da nnkan kan pọ mọ Ọn, ki o maa gbe irun ti a ṣe ni dandan duro, ki o maa yọ saka ti a ṣe ni ọran-anyan, ki o maa gba awẹ Ramadan" O sọ pe: Mo fi ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura mi ko nii lekun lori eyi, nigba ti o pa ẹyin da, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: "Ẹni ti o ba dun mọ ọn lati wo arakunrin kan ninu awọn ara alujanna, ki o yaa wo eyi".
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 1397]
Arakunrin kan ninu awọn ara oko wa ba Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lati tọ ọ sọ́nà lori iṣẹ ti o maa mu u wọ alujanna, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- da a lohun pe dajudaju wiwọ alujanna ati lila kuro nibi ina, méjèèjì duro lori pipe awọn origun Isilaamu, bii ijọsin fun Ọlọhun nikan ṣoṣo, ati ki o si ma da nnkan kan pọ mọ Ọn. Ki o maa gbe irun maraarun-un ti Ọlọhun ṣe wọn ni dandan lori awọn ẹru Rẹ duro ni gbogbo ọsan ati oru. Ki o maa yọ saka owo ti Ọlọhun ṣe ni dandan lori rẹ, ki o si fun ẹni ti o lẹtọọ si i. Ki o maa ṣọ awẹ Ramadan ni asiko rẹ. Arakunrin naa sọ pe mo fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura pe mi ko nii lekun nnkan kan lori iṣẹ ti a ṣe ni ọran-anyan ti mo gbọ́ lọdọ rẹ ninu awọn itẹle, mi ko si nii dinkun ninu rẹ. Nigba ti o pẹyin da, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: Ẹni ti o ba dun mọ ọn ninu lati wo arakunrin kan ninu awọn ara alujanna, ki o yaa wo larubawa oko yii.