عن خَولة الأنصاريةِ رضي الله عنها قالت: سمعت النبي صلى الله عليه وسلم يقول:
«إِنَّ رِجَالًا يَتَخَوَّضُونَ فِي مَالِ اللهِ بِغَيْرِ حَقٍّ، فَلَهُمُ النَّارُ يَوْمَ الْقِيَامَةِ».
[صحيح] - [رواه البخاري] - [صحيح البخاري: 3118]
المزيــد ...
Lati ọdọ Khaolah Al-Ansaariyyah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Mo gbọ ti Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé:
“Dájúdájú àwọn èèyàn kan n wọ inu dúkìá Ọlọhun ni ọ̀nà tí kò tọ́, wọn maa wọ iná ni Ọjọ́ Àjíǹde”.
[O ni alaafia] - [Bukhaariy gba a wa] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 3118]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ nipa awọn eeyan kan ti wọn n ṣe ibajẹ ninu dúkìá àwọn Musulumi, ti wọn si n mu u ni ọ̀nà ti kò tọ́, eyi ni itumọ kan ti o kari nibi dukia, nibi kiko o jọ lati ibi ti ko ti ni ẹtọ, ati nina an sibi ti kii ṣe aaye rẹ ti o tọ, jíjẹ dúkìá àwọn ọmọ orukan maa wọ inú ẹ, àti awọn dúkìá ti a fi sọri awọn kan, ati titako agbafipamọ, ati mimu ninu dúkìá gbogbogboo ni ọ̀nà tí kò tọ́.
Lẹ́yìn náà ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé ẹsan wọn ni iná ni Ọjọ́ Àjíǹde.