عن عائشة رضي الله عنها قالت: سمعتُ من رسول الله صلى الله عليه وسلم يقول في بيتي هذا:
«اللَّهُمَّ مَنْ وَلِيَ مِنْ أَمْرِ أُمَّتِي شَيْئًا فَشَقَّ عَلَيْهِمْ فَاشْقُقْ عَلَيْهِ، وَمَنْ وَلِيَ مِنْ أَمْرِ أُمَّتِي شَيْئًا فَرَفَقَ بِهِمْ فَارْفُقْ بِهِ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 1828]
المزيــد ...
Lati ọdọ Aisha- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Mo gbọ lẹ́nu ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o n sọ ninu ilé mi yii pe:
“Ìwọ Ọlọhun, ẹnikẹni ti o ba jẹ alaṣẹ lori nǹkan kan ninu ijọ mi, ti o wa fi ara ni wọn, ki O fi ara ni in, ẹnikẹni ti o ba jẹ alaṣẹ lori nǹkan kan ninu ijọ mi, ti o wa ṣe pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú wọn, ṣe pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú oun naa”.
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 1828]
Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣẹ èpè lé gbogbo ẹni tí ó bá jẹ alaṣẹ lori àlámọ̀rí kan fun awọn Mùsùlùmí, bóyá o kéré ni tabi o tóbi, bóyá ti gbogbogboo ni tabi fun apá ibikan sọ́, tí o wa fi ara ni wọn ti ko ṣàánú wọn, pe Ọlọhun ti ọla Rẹ ga maa san an lẹsan latara irú iṣẹ rẹ pẹlu pe ki o fi ara ni oun náà.
Ẹni tí ó bá wa ṣàánú wọn ti o si ṣe àlámọ̀rí wọn ni irọrun, pe ki Ọlọhun ṣàánú tiẹ̀ naa ki O si ṣe àlámọ̀rí rẹ ni irọrun.