+ -

قال سعد بن هشام بن عامر -عندما دخل على عائشة رضي الله عنها-:
يَا أُمَّ الْمُؤْمِنِينَ، أَنْبِئِينِي عَنْ خُلُقِ رَسُولِ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، قَالَتْ: أَلَسْتَ تَقْرَأُ الْقُرْآنَ؟ قُلْتُ: بَلَى، قَالَتْ: فَإِنَّ خُلُقَ نَبِيِّ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ كَانَ الْقُرْآنَ.

[صحيح] - [رواه مسلم في جملة حديثٍ طويلٍ]
المزيــد ...

Sa‘d ọmọ Hishām ọmọ ‘Āmir sọ – nigba ti o wọlé tọ ‘Āisha – ki Ọlọhun yọnu si i pé-:
Irẹ iya awa mu’mini, fun mi ni iro nipa iwa Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – o sọ pe: Ṣe iwọ o ki n ka Alukurāni ni? Mo sọ pe: Mo maa n ka a, o sọ pe: Dajudaju iwa Anabi Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ni Kuraani.

O ni alaafia - Muslim gba a wa

Àlàyé

Wọn bi iya awa mu’mini ‘Āisha – ki Ọlọhun yọnu si i – leere nipa iwa Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, o si fún wọn ní esi pẹlu gbólóhùn ṣókí kan ti o ko nkan ti o pọ sinu, o si tun ṣẹri onibeere sibi Kuraani Alapọn-ọnle eleyii ti o ko gbogbo iroyin ti o pe sinu, nígbà náà ni o wa sọ pe: O jẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ẹni tí maa n wuwa pẹlu awọn iwa Alukurāni. Alukurāni o nii pàṣẹ pẹlu nkankan ayaafi ki o ṣe é, ko si nii kọ kuro nibi nkankan ayaafi ki o jina si i, nitori naa iwa rẹ ni ṣiṣe iṣẹ pẹlu rẹ (Alukurāni), ati diduro nibi awọn aala rẹ, ati lilo ẹkọ pẹlu awọn ẹkọ rẹ, ati ṣiṣe ariwoye pẹlu awọn àkàwé rẹ àti awọn itan rẹ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè Somalia
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣiṣenilojukokoro lori ikọṣe Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – nibi iwuwasi rẹ pẹlu awọn iwa Alukurāni.
  2. Yiyin awọn iwa ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ati pe ninu òpó àtùpà imisi l’o ti wa.
  3. Alukurāni ipilẹ l’o jẹ fun gbogbo awọn iwa alapọn-ọnle.
  4. Awọn iwa ninu Isilāmu ko gbogbo ẹsin sinu pẹlu ṣiṣe awọn aṣẹ ati jijina sí awọn eewọ.