عن أبي هريرة رضي الله عنه قال:
كان رسولُ الله صلى الله عليه وسلم إذا عَطَس وضَعَ يَدَه -أو ثوبَهُ- على فيهِ، وخَفَضَ -أو غضَّ- بها صوتَهُ.
[صحيح] - [رواه أبو داود والترمذي وأحمد] - [سنن أبي داود: 5029]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Hurayra– ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe:
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba sin, o maa n gbe ọwọ rẹ- tabi aṣọ rẹ- si ẹnu rẹ, ti o maa fi rẹ ohun rẹ nilẹ.
[O ni alaafia] - [Abu Daud ati Tirmiziy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa] - [Sunanu ti Abu Daud - 5029]
Ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba sin, o maa n:
Akọkọ: O maa gbe ọwọ rẹ, tabi aṣọ rẹ sori ẹnu rẹ; ki nnkan kan ma baa jade lati ẹnu rẹ tabi imu rẹ ti o le ko suta ba alabajokoo rẹ.
Ikeji: O maa n rẹ ohun rẹ nilẹ, ko si nii gbe e soke.