+ -

عَنْ عَائِشَةَ أُمِّ المؤمنين رضي الله عنها قَالَتْ:
كَانَ رَسُولُ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ إِذَا اغْتَسَلَ مِنَ الجَنَابَةِ، غَسَلَ يَدَيْهِ، وَتَوَضَّأَ وُضُوءَهُ لِلصَّلاَةِ، ثُمَّ اغْتَسَلَ، ثُمَّ يُخَلِّلُ بِيَدِهِ شَعَرَهُ، حَتَّى إِذَا ظَنَّ أَنَّهُ قَدْ أَرْوَى بَشَرَتَهُ، أَفَاضَ عَلَيْهِ المَاءَ ثَلاَثَ مَرَّاتٍ، ثُمَّ غَسَلَ سَائِرَ جَسَدِهِ، وَقَالَتْ: كُنْتُ أَغْتَسِلُ أَنَا وَرَسُولُ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ مِنْ إِنَاءٍ وَاحِدٍ، نَغْرِفُ مِنْهُ جَمِيعًا.

[صحيح] - [رواه البخاري] - [صحيح البخاري: 272]
المزيــد ...

Lati ọdọ Aaisha Iya awọn Mumuni - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe:
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o ṣe pe ti o ba ti fẹ wẹ janaba, yio fọ ọwọ rẹ mejeeji, yio si tun ṣe aluwala rẹ ti maa n ṣe fun irun, lẹyin naa yio wẹ, lẹyin naa yio fi ọwọ rẹ mejeeji ya irun rẹ, titi ti yio fi ro ni ẹmi rẹ pe o ti kan awọ isalẹ irun rẹ, yio wa da omi si ara ni ẹẹmẹta, lẹyin naa yio wẹ ara rẹ yoku, ni o wa sọ pe: Mo jẹ ẹni ti emi pẹlu ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - maa n wẹ papọ ninu igba kan náà, ti a si jọ maa n fi ọwọ bu omi papọ ninu rẹ.

[O ni alaafia] - [Bukhaariy gba a wa] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 272]

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o ṣe pe ti o ba fẹ wẹ janaba yio bẹrẹ pẹlu fifọ ọwọ rẹ mejeeji, Lẹyin naa ni yio wa ṣe aluwala gẹgẹ bi o ṣe maa n ṣe aluwala fun irun, lẹyin naa yio fi ọwọ rẹ mejeeji ya irun ori rẹ, titi ti yio fi ni lọkan pe omi ti de isalẹ irun, ti o si ti jẹ ki awọ ori mumi yo, yio waa da omi si ori ni ẹẹmẹta lẹyin naa yio wẹ ara rẹ yoku. Aaisha - ki Ọlọhun yọnu si i - wa sọ pe: Mo jẹ ẹni ti emi pẹlu ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - maa n wẹ ninu igba kan náà ti a o jọ maa fi ọwọ bu omi ninu rẹ papọ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Ede Jamani Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè Czech Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada Ti èdè ìlú Ukraine
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Iwẹ iran meji ni: Eyiti o toni ati eyiti o pe, ẹẹ wa ri iwẹ ti o toni, ọmọnìyàn o da aniyan imọra, lẹyin naa yio fi omi kari gbogbo ara rẹ pẹlu fifi omi yọ ẹnu ati fifin omi si imu, ṣugbọn iwẹ ti o pe, yio wẹ gẹgẹ bi Anabi ṣe wẹ ninu hadīth yii.
  2. Wọn maa n lo Janaba fun gbogbo ẹni ti o ba da atọ si ara, tabi ti o ba ni ibalopọ koda ki o ma da atọ.
  3. Jijẹ ẹtọ ki ọkọ ati iyawo o maa wo ihoho ara wọn, ati ki wọn maa wẹ papọ ninu igba kan naa.