+ -

عن أبي هريرة قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«حَقٌّ عَلَى كُلِّ مُسْلِمٍ أَنْ يَغْتَسِلَ فِي كُلِّ سَبْعَةِ أَيَّامٍ يَوْمًا، يَغْسِلُ فِيهِ رَأْسَهُ وَجَسَدَهُ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 897]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Hurayra o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe:
«Ẹtọ ni lori gbogbo Musulumi ki o wẹ ni ọjọ kan ninu gbogbo ọjọ meje, ti yio wẹ ori rẹ ati ara rẹ».

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 897]

Àlàyé

Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – royin pe: Dajudaju iwọ ti wọn kanpa mọ lori gbogbo Musulumi ti o ti balaga ti o ni laakaye ni ki o wẹ ni ọjọ kan ninu gbogbo ọjọ meje inu ọsẹ, nitori naa yio wẹ ni ọjọ yii ori rẹ ati ara rẹ, lati fi wa imọra ati imọtoto, ati pe eyi ti o lọla ju ninu awọn ọjọ yii ni ọjọ jimọ, gẹgẹ bi wọn ṣe gbọ ọ ye ninu awọn ẹgbawa miran, ati pe wiwẹ ni ọjọ jimọ siwaju irun, nkan ti wọn fẹ (sunnah) ni ti fifẹ ti wọn kanpa mọ ni, koda ki o wẹ ni ọjọ alaamisi fun apẹrẹ, ati pe nkan ti o gbe ijẹ dandan yẹn kuro ni gbolohun ‘Aisha – ki Ọlọhun yọnu si i – pe: “Awọn eeyan jẹ oṣiṣẹ ara wọn, wọn si tun jẹ ẹni ti o ṣe pe ti wọn ba lọ fun jimọ wọn yio lọ pẹlu irisi wọn: Ni wọn wa sọ fun wọn pe: Ẹẹ ba si wa wẹ”, Bukhari lo gba a wa, ati pe ninu ẹgbawa miran fun un (Bukhari): “Wọn ni awọn oorun” iyẹn ni pe oorun oogun ati nkan ti o jọ ọ, pẹlu bẹẹ wọn sọ fun wọn pe: “Ẹẹ ba si wẹ”, nitori naa ẹni ti o yatọ si wọn lo wa ni ipo ki o ṣe e (Iwẹ) ju awọn lọ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Tọ́kì Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Burmese Thai Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè Czech Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada Ti èdè ìlú Ukraine
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Akolekan Isilaamu pẹlu ìmọ́tótó ati imọra.
  2. Iwẹ jimọ nkan ti wọn fẹ (sunnah) ni ni ti fifẹ ti wọn kanpa mọ fun irun.
  3. Didarukọ ori bo tiẹ jẹ wipe didarukọ ara maa ko o sinu; lati le ni akolekan pẹlu rẹ ni.
  4. Iwẹ jẹ dandan fun gbogbo ẹni ti wọn ba ri oorun ti ko daa ti awọn eeyan le maa ri inira pẹlu rẹ ni ara rẹ.
  5. Ọjọ ti o fi n kanpa julọ fun iwẹ (sunnah) ni ọjọ jimọ; latari ọla rẹ.