عن قيس بن عاصم رضي الله عنه قال:
أتيتُ النبيَّ صلى الله عليه وسلم أُريدُ الإسلامَ، فأَمَرَني أن أغتَسِلَ بماءٍ وسِدرٍ.

[صحيح] - [رواه أبو داود والترمذي والنسائي] - [سنن أبي داود: 355]
المزيــد ...

Lati ọdọ Qays ọmọ ‘Aasim- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe:
Mo lọ ba Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe mọ fẹ gba Isilaamu, o wa pa mi láṣẹ lati wẹ pẹlu omi ati ewe sidiru.

[O ni alaafia] - [Abu Daud ati Tirmiziy ati Nasaa'iy ni wọn gba a wa] - [Sunanu ti Abu Daud - 355]

Àlàyé

Qays ọmọ ‘Aasim wa ba Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o si fẹ gba Isilaamu, ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba pa a láṣẹ lati wẹ pẹlu omi ati ewe sidiru; ki o le fi ewe rẹ mọra; ati fun nnkan ti o n bẹ fun un ninu oorun dídùn.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣíṣe lofin wiwẹ alaigbagbọ nigba ti o ba fẹ wọnu Isilaamu.
  2. Iyi ti o n bẹ fun Isilaamu ati iko akolekan rẹ pẹlu ara ati ẹmi papọ.
  3. Iropọ omi pẹlu awọn nnkan ti wọn mọ ko mu u jade kuro nibi ijẹ mimọ rẹ.
  4. Awọn nnkan ti o maa n mọ nnkan ti igbalode maa dipo sidiru, gẹgẹ bii ọṣẹ ati nnkan ti o jọ ọ.
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Èdè: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Àlékún (58)